Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Mọ̀ Wá

Ó Mọ̀ Wá

Wà á jáde:

  1. 1. Kò sóhun tó pa mọ́ lójú Jèhófà,

    Torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa,

    Ó mọ̀ wá kí wọ́n tó bí wa

    Ìmọ̀ rẹ̀ kọjá òye wa.

    Àgbàyanu lèyí jẹ́!

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà rọ́kàn wa

    Ó rí wa bá a ṣe jẹ́,

    Bá a ṣe ń sa gbogbo ipá wa,

    Láti máa ṣe ohun tó fẹ́.

    Jèhófà rọ́kàn wa

    Ó mohun tí a fẹ́.

    Bíṣòro bá pọ̀ lápọ̀jù, tí nǹkan sú wa,

    Ó mọ̀.

  2. 2. Baba onífẹ̀ẹ́ ni Ọlọ́run wa,

    Ó sì fẹ́ kí a ṣạ̀seyọrí

    Ibi tí a dáa sí ló máa ń wò,

    Kì í wo àwọn ibi tá a kù sí.

    Ìfẹ́ tó ní sí wa ga!

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà rọ́kàn wa

    Ó rí wa bá a ṣe jẹ́,

    Bá a ṣe ń sa gbogbo ipá wa,

    Láti máa ṣe ohun tó fẹ́.

    Jèhófà rọ́kàn wa.

    Ó mohun tí a fẹ́,

    Bíṣòro bá pọ̀ lápọ̀jù, tí nǹkan sú wa.

    Ó mọ̀.

    (ÀSOPỌ̀)

    Tíṣòro bá dé bá wa, ká rántí pé ìfẹ́ Ọlọ́run kì í yẹ̀, kì í yẹ̀.

    Ẹ jẹ́ ká gbàdúrà, ká sọ bó ṣe rí lára wa.

    Ọlọ́run yóò gbọ́ wa, yóò fi wá lọ́kàn balẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà rọ́kàn wa,

    Ó rí wa bá a ṣe jẹ́,

    Bá a ṣe ń sa gbogbo ipá wa,

    Láti máa ṣe ohun tó fẹ́.

    Jèhófà rọ́kàn wa,

    Ó mohun tí a fẹ́.

    Bíṣòro bá pọ̀ lápọ̀jù, tí nǹkan sú wa.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà rọ́kàn wa,

    Ó rí wa bá a ṣe jẹ́,

    Bá a ṣe ń sa gbogbo ipá wa,

    Láti máa ṣe ohun tó fẹ́.

    Jèhófà rọ́kàn wa.

    Ó mohun tí a fẹ́,

    Bíṣòro bá pọ̀ lápọ̀jù, tí nǹkan sú wa,

    Ó mọ̀.