Ọ̀rẹ́ Tòótọ́
Wà á jáde:
1. Kò rọrùn rárá ní àkókò yìí láti wà láìlọ́rẹ̀ẹ́.
Jèhófà mọ̀ pé a nílò ọ̀rẹ́ gidi láyé wa
Ibo wá ni a ti máa rọ́rẹ̀ẹ́ gidi tó ṣeé fọkàn tán?
Ká rántí ohun tí Bíbélì sọ.
(ÈGBÈ)
Ọ̀rẹ́
Tòótọ́ ń gbéni ró,
Ó máa ń báni yọ̀,
Á dúró tì ẹ́ n’gbà ‘ṣòro,
A bá ẹ sòótọ́,
Á gbóríyìn fún ẹ,
Á jẹ́ kó o sáré ìyè dópin,
Kò ní jẹ́ kó o fi Jèhófà sílẹ̀ láé.
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni.
2. Ìfẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ kì í yẹ̀, Bíbélì ti sọ bẹ́ẹ̀.
Tí ìṣòro bá dé, ẹ ò gbọ́dọ̀ jà. Gbàdúrà; jẹ́ kó tán.
Àtàgbalagbà àti ọmọdé, ó yẹ ká wà ní ìṣọ̀kan.
Párádísè tó ń bọ̀, ó ti dé tán.
(ÈGBÈ)
Ọ̀rẹ́
Tòótọ́ ń gbéni ró,
Ó máa ń báni yọ̀,
Á dúró tì ẹ́ n’gbà ‘ṣòro,
A bá ẹ sòótọ́,
Á gbóríyìn fún ẹ,
Á jẹ́ kó o sáré ìyè dópin,
Kò ní jẹ́ kó o fi Jèhófà sílẹ̀ láé.
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni.
(ÀSOPỌ̀)
Ọ̀rẹ́ gidi,
Tá a jẹ́ kó o lè máa sin Jèhófà Ọlọ́run,
Ó máa dúró tì ẹ́, á tún fún ẹ níṣìírí
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni.
(ÈGBÈ)
Ọ̀rẹ́
Tòótọ́ ń gbéni ró,
Ó máa ń báni yọ̀,
Á dúró tì ẹ́ n’gbà ‘ṣòro,
A bá ẹ sòótọ́,
Á gbóríyìn fún ẹ,
Á jẹ́ kó o sáré ìyè dópin,
Kò ní jẹ́ kó o fi Jèhófà sílẹ̀ láé.
(ÈGBÈ)
Ọ̀rẹ́
Tòótọ́ ń gbéni ró,
Ó máa ń báni yọ̀,
Á dúró tì ẹ́ n’gbà ‘ṣòro,
A bá ẹ sòótọ́,
Á gbóríyìn fún ẹ,
Á jẹ́ kó o sáré ìyè dópin,
Kò ní jẹ́ kó o fi Jèhófà sílẹ̀ láé.
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni.
Ọ̀rẹ́ tòótọ́.
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni.