Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Owó Kéékèèké Méjì”

“Owó Kéékèèké Méjì”

Wà á jáde:

  1. 1. Nígbà kan

    Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mò ń ṣe.

    Mo máa ń lọ

    Sóde ẹ̀rí, mò ń ṣiṣẹ́ ìrànwọ́.

    Lásìkò yìí,

    Mi ò lè ṣe tó bẹ́ẹ̀ mọ́.

    Ṣé Jèhófà mọyì

    Ohun tí agbára mi gbé?

    (ÈGBÈ)

    Ohun tí mò ń ṣe,

    Jọ ẹyọ owó,

    Tí opó kan fi ṣe ọrẹ.

    Eyọ méjì péré

    Jèhófà mọyì mi

    Torí ó mọyì owó

    Tó fi tọrẹ.

  2. 2. Gbogbo ohun

    Tó ní ló fi ṣe ọrẹ

    Àwọn ọlọ́rọ̀

    Ń  ṣe ọrẹ tó pọ̀ ju tirẹ̀ lọ gan-an.

    Jésù wa sọ pé,

    ẹ̀bùn rẹ̀ ṣeyebíye.

    Ó kéré lójú wa,

    Sùgbọ́n Baba mọyì ẹ̀bùn yẹn.

    (ÈGBÈ)

    Ohun tí mò ń ṣe,

    Jọ ẹyọ owó,

    Tí opó kan fi ṣe ọrẹ.

    Eyọ méjì péré

    Jèhófà mọyì mi

    Torí ó mọyì owó

    Tó fi tọrẹ.

    (ÀSOPỌ̀)

    Jèhófà tóbi ju ọkàn wa lọ

    Ó mọ̀ wá ju bí a ṣe lérò lọ.

    A mọ̀ pó nífẹ̀ẹ́ wa.

    (ÈGBÈ)

    Ohun tí à ń ṣe,

    Jọ ẹyọ owó,

    Tí opó kan fi ṣe ọrẹ

    Eyọ méjì péré

    Jèhófà mọyì wa

    Torí ó mọyì owó tó

    Fi ṣe ọrẹ.

    Ó tóbi ju ọkàn wa lọ.