Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 116

Agbára Inúure

Agbára Inúure

(Éfésù 4:32)

  1. 1. Tọkàntọkàn là ń yìn ọ́, Jèhófà

    Torí pé Ọ̀rọ̀ rẹ

    Jẹ́ ká mọ bágbára rẹ ṣe pọ̀ tó,

    Síbẹ̀ ò ń fìfẹ́ hàn sí wa.

  2. 2. Jésù ń pe àwọn tẹ́rù wọn wúwo

    Kí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

    Onínúure ni, onírẹ̀lẹ̀ ni;

    Ó máa mú ìtura bá wọn.

  3. 3. Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀

    Ti fàpẹẹrẹ lélẹ̀.

    Tá a bá jẹ́ onínúure bíi tiwọn,

    Yóò sọ wá di alágbára!