ORIN 119
Ó Yẹ Ká Ní Ìgbàgbọ́
-
1. Ọlọ́run bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀
Nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀.
Lónìí, ó ń lo Ọmọ rẹ̀ láti sọ
Pé ká ronú pìwà dà.
(ÈGBÈ)
Ṣé a nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀?
Ohun tá à ń ṣe gbọ́dọ̀ fi hàn.
Ìgbàgbọ́ yìí ṣe pàtàkì;
Ìgbàgbọ́ wa yóò mú kí á níyè.
-
2. À ń fi ayọ̀ tẹ̀ lé àṣẹ Jésù
Pé ká wàásù ìhìn rere.
À ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ìrètí
Tí Ọlọ́run ṣèlérí.
ÈGBÈ)
Ṣé a nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀?
Ohun tá à ń ṣe gbọ́dọ̀ fi hàn.
Ìgbàgbọ́ yìí ṣe pàtàkì;
Ìgbàgbọ́ wa yóò mú kí á níyè.
-
3. Ìdákọ̀ró ni ìgbàgbọ́ wa jẹ́,
Yóò jẹ́ ká lè nífaradà.
Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jáà, a ò ní bẹ̀rù;
Torí ìgbàlà dé tán.
ÈGBÈ)
Ṣé a nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀?
Ohun tá à ń ṣe gbọ́dọ̀ fi hàn.
Ìgbàgbọ́ yìí ṣe pàtàkì;
Ìgbàgbọ́ wa yóò mú kí á níyè.
(Tún wo Róòmù 10:10; Éfé. 3:12; Héb. 11:6; 1 Jòh. 5:4.)