ORIN 122
Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin
-
1. Hílàhílo ti dé bá aráyé;
Wọn kò mọ ohun tá á ṣẹlẹ̀ lọ́la.
Ó yẹ káwa fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin,
Ká fòótọ́ sin Ọlọ́run.
(ÈGBÈ)
Ó yẹ ká dúró ṣinṣin,
Ká má ṣe báyé ṣọ̀rẹ́.
Kí á jẹ́ olóòótọ́,
Ká lè jogún ìyè.
-
2. Ìdẹwò pọ̀ gan-an nínú ayé yìí.
Èrò tó tọ́ yóò mú ká borí wọn.
Tá a bá kórìíra ohun tó burú,
Yóò jẹ́ kẹ́sẹ̀ wa múlẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ó yẹ ká dúró ṣinṣin,
Ká má ṣe báyé ṣọ̀rẹ́.
Kí á jẹ́ olóòótọ́,
Ká lè jogún ìyè.
-
3. Ká jọ́sìn Ọlọ́run látọkàn wá;
Ká sì tẹra mọ́ iṣẹ́ Olúwa.
Ká wàásù Ìjọba náà fáráyé;
Òpin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.
(ÈGBÈ)
Ó yẹ ká dúró ṣinṣin,
Ká má ṣe báyé ṣọ̀rẹ́.
Kí á jẹ́ olóòótọ́,
Ká lè jogún ìyè.
(Tún wo Lúùkù 21:9; 1 Pét. 4:7.)