Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 130

Ẹ Máa Dárí Jini

Ẹ Máa Dárí Jini

(Sáàmù 86:5)

  1. 1. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa;

    Ó fún wa ní Ọmọ rẹ̀,

    Kó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wá,

    Kó sì mú ikú kúrò.

    Tí a bá ronú pìwà dà,

    Yóò dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wá.

    Lọ́lá ìràpadà Kristi,

    Ọlọ́run yóò gbẹ́bẹ̀ wa.

  2. 2. Tá a bá ńdárí jini,

    Tá a fara wé Ọlọ́run,

    Tá a nífẹ̀ẹ́, tá à ń gba tẹni rò,

    Àwa náà máa ráàánú gbà.

    Ká máa fara dà á fúnra wa,

    Ká má ṣe máa bínú jù.

    Ká máa bọlá fáwọn ará;

    Ìyẹn ni ìfẹ́ tòótọ́.

  3. 3. Àánú ṣe pàtàkì.

    Ó yẹ ká jẹ́ aláàánú.

    Ká má ṣe dira wa sínú,

    Ká sì fẹ́ràn ara wa.

    Táa bá ńfara wé Jèhófà,

    Ẹni tífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ga jù,

    Aó máa dárí ji ara wa

    Látọkàn wá, láìṣẹ̀tàn.