ORIN 137
Àwọn Obìnrin Olóòótọ́, Àwọn Arábìnrin Wa
-
1. A ní àwọn obìnrin tó jólóòótọ́.
Lára wọn ni Sérà, Ẹ́sítà, Rúùtù.
Màríà kò gbẹ́yìn; wọ́n fọkàn sin Jáà.
Adúróṣinṣin làwọn obìnrin yìí.
Ọ̀pọ̀ ló wà tá ò morúkọ wọn,
Àmọ́ ìgbàgbọ́ wọn jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa.
-
2. Àwọn ànímọ́ tó dáa táráyé ń fẹ́—
Ìṣòtítọ́, ìgboyà, inú rere,
Làwọn obìnrin dáadáa wọ̀nyí gbé yọ.
Wọ́n jẹ́ àwòkọ́ṣe tó dára fún wa.
Lónìí náà, àwọn arábìnrin wa
Jẹ́ adúróṣinṣin, a sì mọyì wọn gan-an.
-
3. Gbogbo ẹ̀yin arábìnrin wa ọ̀wọ́n,
Tẹ́ ẹ ń fìdùnnú ṣiṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.
Onírẹ̀lẹ̀ ni yín, ẹ máa ń tẹrí ba.
Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ yín, ẹ má ṣe bẹ̀rù.
Jèhófà kò ní fi yín sílẹ̀ láé;
Ẹ fọkàn yín balẹ̀, èrè yín ti dé tán!
(Tún wo Fílí. 4:3; 1 Tím. 2:9, 10; 1 Pét. 3:4, 5.)