Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 146

Ọlọ́run Máa “Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”

Ọlọ́run Máa “Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”

(Ìfihàn 21:1-5)

  1. 1. Ìjọba Jèhófà Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀.

    Jésù ti gúnwà sórí ìtẹ́ rẹ̀.

    Ibùgbé Èṣù kò sí lọ́run mọ́.

    Láìpẹ́, ìfẹ́ Ọlọ́run la ó máa ṣe.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ yọ̀! Jáà yóò máa bá wa gbé.

    Àgọ́ rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wa.

    Kò ní sẹ́kún àti ìrora mọ́.

    Ọ̀fọ̀, oró ikú kò ní sí mọ́.

    Ọlọ́run yóò sohun gbogbo dọ̀tun.

    Òdodo àtòótọ́ ni.

  2. 2. Ẹ wá wo Jerúsálẹ́mù tuntun náà,

    Ìyàwó ọ̀dọ́ àgùntàn ń tàn yòò.

    A ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, ó sì rẹwà púpọ̀.

    Jèhófà lorísun ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ yọ̀! Jáà yóò máa bá wa gbé.

    Àgọ́ rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wa.

    Kò ní sẹ́kún àti ìrora mọ́.

    Ọ̀fọ̀, oró ikú kò ní sí mọ́.

    Ọlọ́run yóò sohun gbogbo dọ̀tun.

    Òdodo àtòótọ́ ni.

  3. 3. Ìlú yìí yóò múnú gbogbo èèyàn dùn.

    Ibodè rẹ̀ yóò máa wà ní ṣíṣí.

    Ògo rẹ̀ yóò tàn sórí aráyé;

    Àwọn ìránṣẹ́ Jáà ń fògo rẹ̀ hàn.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ yọ̀! Jáà yóò máa bá wa gbé.

    Àgọ́ rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wa.

    Kò ní sẹ́kún àti ìrora mọ́.

    Ọ̀fọ̀, oró ikú kò ní sí mọ́.

    Ọlọ́run yóò sohun gbogbo dọ̀tun.

    Òdodo àtòótọ́ ni.