ORIN 43
Àdúrà Ìdúpẹ́
-
1. Bàbá aláàánú, jọ̀ọ́ gbọ́ àdúrà wa.
Jèhófà, a dúpẹ́, a sì yìn ọ́.
A gbẹ́kẹ̀ lé ọ, à ń sìn ọ́ látọkàn
Torí a mọ̀ pé ò ń ṣìkẹ́ wa gan-an.
Àìpé ń jẹ́ ká ṣàṣìṣe lójoojúmọ́.
Jọ̀ọ́, dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.
A dúpẹ́ gan-an pé o ti rà wá pa dà,
Tó o sì tún mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá.
-
2. A mọrírì ìfẹ́ àti àánú rẹ
Àti bí o ṣe tún ń fà wá mọ́ra.
Jẹ́ ká lè máa sìn ọ́, kọ́ wa ká mọ̀ ọ́,
Ká jẹ́ olóòótọ́, ká dúró ṣinṣin.
A dúpẹ́ pé ò ń fẹ̀mí rẹ darí wa.
Ò ń fún wa nígboyà ká lè wàásù.
A dúpẹ́ pé o máa ń ṣojúure sí wa.
A ó máa fayọ̀ àtìrẹ̀lẹ̀ sìn ọ́.