ORIN 46
A Dúpẹ́, Jèhófà
-
1. A dúpẹ́ Jèhófà, fún ìmọ́lẹ̀ rẹ
Tó ń tàn sórí wa ní ojoojúmọ́.
A dúpẹ́ pé a lè gbàdúrà sí ọ,
Tá a lè sọ gbogbo ‘ṣòro wa fún ọ.
-
2. A dúpẹ́ Jèhófà fọ́mọ rẹ ọ̀wọ́n,
Tó fìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣẹ́gun ayé yìí.
A dúpẹ́, ò ń tọ́ wa ká lè ṣèfẹ́ rẹ,
Ká sì lè mú àwọn ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.
-
3. A dúpẹ́ pá a láǹfààní láti wàásù
Nípa òtítọ́ àt’orúkọ rẹ.
A dúpẹ́ pé ìṣòro máa tán láìpẹ́,
Ìbùkún ‘jọba rẹ yóò wà láéláé.
(Tún wo Sm. 50:14; 95:2; 147:7; Kól. 3:15.)