Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 50

Àdúrà Ìyàsímímọ́ Mi

Àdúrà Ìyàsímímọ́ Mi

(Mátíù 22:37)

  1. 1. Màá sìn ọ́ tọkàntọkàn.

    Fún mi lọ́gbọ́n àtòye.

    Màá fi ohùn mi yìn ọ́;

    Màá fi kọrin ìyìn rẹ.

  2. 2. Gba ọwọ́ àtẹsẹ̀ mi;

    Kí wọ́n máa pàṣẹ rẹ mọ́.

    Gba gbogbo ìṣúra mi;

    Mo fún ọ pátápátá.

  3. 3. Mo fi ayé mi fún ọ.

    Màá ṣohun tó o bá ti fẹ́.

    Jẹ́ kí n máa múnú rẹ dùn

    Jálẹ̀ ọjọ́ ayé mi.