Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 57

Máa Wàásù fún Onírúurú Èèyàn

Máa Wàásù fún Onírúurú Èèyàn

(1 Tímótì 2:4)

  1. 1. A fẹ́ fi ìwà jọ Ọlọ́run wa,

    Torí Jèhófà kì í ṣojúsàájú.

    Gbogbo onírúurú èèyàn ló ń pè,

    Kí wọ́n dọ̀rẹ́ rẹ̀, kó lè gbà wọ́n là.

    (ÈGBÈ)

    Ibi yòówù kí wọ́n wà,

    Ọkàn ló ṣe pàtàkì.

    Onírúurú àwọn èèyàn là ńwá.

    Torí náà, ẹ jẹ́ ká lọ

    Wàásù ní ibi gbogbo

    Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.

  2. 2. Ibi yòówù kí a ti lè rí wọn,

    Bí wọ́n ṣe rí kọ́ ló ṣe pàtàkì.

    Ṣùgbọ́n bí inú ọkàn wọn ṣe rí

    Ló ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà.

    (ÈGBÈ)

    Ibi yòówù kí wọ́n wà,

    Ọkàn ló ṣe pàtàkì.

    Onírúurú àwọn èèyàn là ńwá.

    Torí náà, ẹ jẹ́ ká lọ

    Wàásù ní ibi gbogbo

    Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.

  3. 3. Gbogbo àwọn tó ti ṣe ìpinnu

    Láti fàwọn ìwà ayé sílẹ̀,

    La mọ̀ pé Jèhófà máa tẹ́wọ́ gbà,

    À ń lọ wàásù kí aráyé lè mọ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ibi yòówù kí wọ́n wà,

    Ọkàn ló ṣe pàtàkì.

    Onírúurú àwọn èèyàn là ńwá.

    Torí náà, ẹ jẹ́ ká lọ

    Wàásù ní ibi gbogbo

    Káwọn èèyàn lè dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.