ORIN 67
Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà
-
1. Jáà ti pàṣẹ fún wa lónìí,
Ó sì yẹ ká ṣègbọràn sáṣẹ rẹ̀.
Ká máa múra ọkàn wa sílẹ̀
Láti sọ̀r’Ọlọ́run nígbàkigbà.
(ÈGBÈ)
Ṣáà máa wàásù
Kí gbogbo èèyàn lè gbọ́.
Máa wàásù;
Òpin ayé ti dé tán.
Máa wàásù;
Kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́.
Máa wàásù
Kárí ayé.
-
2. Àkókò ìṣòro yóò wà.
Wọ́n lè ṣe inúnibíni sí wa.
Bí wọn kò tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa,
Ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run wa.
(ÈGBÈ)
Ṣáà máa wàásù
Kí gbogbo èèyàn lè gbọ́.
Máa wàásù;
Òpin ayé ti dé tán.
Máa wàásù;
Kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́.
Máa wàásù
Kárí ayé.
-
3. Àkókò tó dẹrùn yóò wà,
Táa máa ní àǹfààní láti kọ́ni.
Ká wàásù kí wọ́n lè rígbàlà,
Kórúkọ Jèhófà lè di mímọ́.
(ÈGBÈ)
Ṣáà máa wàásù
Kí gbogbo èèyàn lè gbọ́.
Máa wàásù;
Òpin ayé ti dé tán.
Máa wàásù;
Kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́.
Máa wàásù
Kárí ayé.
(Tún wo Mát. 10:7; 24:14; Ìṣe 10:42; 1 Pét. 3:15.)