ORIN 75
“Èmi Nìyí! Rán Mi!”
-
1. Aráyé ń pẹ̀gàn Ọlọ́run.
Wọ́n ń b’orúkọ mímọ́ rẹ̀ jẹ́.
Wọ́n tún ń sọ pé ọ̀dájú ni.
Wọ́n tiẹ̀ ń sọ pé, “Kò s’Ọ́lọ́run.”
Ta ló máa mẹ́gàn yìí kúrò,
Tó máa gbèjà orúkọ rẹ̀?
(ÈGBÈ 1)
Olúwa, èmi rèé! Rán mi!
Màá ròyìn iṣẹ́ rẹ fáyé.
Ọlá ńlá lo dá mi, Olúwa.
Èmi rèé! Rán mi, rán mi.
-
2. Àwọn èèyàn kan ń bọ̀rìṣà.
Ọba ayé ló ń darí wọn.
Wọ́n sọ pé Jáà ń fi nǹkan falẹ̀;
Wọn kò níbẹ̀rù Ọlọ́run.
Ta ló máa kìlọ̀ fẹ́ni ‘bi
Pé Amágẹ́dọ́nì dé tán?
(ÈGBÈ 2)
Olúwa, èmi rèé! Rán mi!
Màá fìgboyà kìlọ̀ fún wọn.
Ọlá ńlá lo dá mi, Olúwa.
Èmi rèé! Rán mi, rán mi.
-
3. Onírẹ̀lẹ̀ ń kérora gan-an
Torí ìwà ibi ń pọ̀ sí i.
Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń wá
Òtítọ́ tó ń fọkàn balẹ̀.
Ta ló máa lọ tù wọ́n nínú,
Táá kọ́ wọn lọ́nà òdodo?
(ÈGBÈ 3)
Olúwa, èmi rèé! Rán mi!
Màá fi sùúrù kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.
Ọlá ńlá lo dá mi, Olúwa.
Èmi rèé! Rán mi, rán mi.