ORIN 83
“Láti Ilé dé Ilé”
-
1. À ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Láti ilé délé.
Iṣẹ́ ìwàásù wa ń kárí
Gbogbo ilẹ̀ ayé.
Tọmọdé tàgbà wa ló ń ṣe
Iṣẹ́ pàtàkì yìí.
Káwọn èèyàn bàa lè mọ̀ pé
Jésù ti ń ṣàkóso.
-
2. Báwo laráyé ṣe máa gbọ́
Láìsí oníwàásù?
Báwo ni wọ́n ṣe máa ké pe
Ẹni tí wọn kò mọ̀?
Ó pọn dandan fún wa láti
Kọ́ wọn lọ́r’Ọlọ́run.
Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe yìí
Máa jẹ́ kí wọ́n gbà là.
-
3. Kí gbogbo wa lọ máa wàásù
Ìròyìn ayọ̀ náà.
Ó kù sọ́wọ́ àwọn èèyàn
Láti yàn fúnra wọn.
Ká jẹ́ kí gbogbo aráyé
Morúkọ Jèhófà,
Kí wọ́n sì fìyìn fún Jésù
Àti Ìjọba Rẹ̀.
(Tún wo Ìṣe 2:21; Róòmù 10:14.)