Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 90

Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú

Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú

(Hébérù 10:24, 25)

  1. 1. Bá a ṣe ńkóra jọ láti jọ́sìn,

    Tí à ń fòótọ́ inú sin Jáà,

    À ń ru àwọn ará wa sókè;

    Sífẹ̀ẹ́ àti iṣẹ́ rere.

    Ibi ààbò ni ìjọ wa jẹ́,

    Ọkàn wa máa ń balẹ̀ níbẹ̀.

    Àlàáfíà wà láàárín gbogbo wa,

    A nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú.

  2. 2. Ọ̀rọ̀ tá a sọ lákòókò tó yẹ

    Máa ń tura, ó sì ńgbéni ró!

    Ó máa ń jẹ́ káwọn tó sorí kọ́

    Rítùnú, kí wọ́n sì láyọ̀.

    Bí a ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan,

    À ń wọ̀nà fún ayé tuntun!

    À ń gbéra wa ró, a sì ńlókun;

    A tún ń dúró ti ara wa.

  3. 3. Ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé.

    Ojú ìgbàgbọ́ la fi ń rí i.

    Torí náà, a ó máa pé jọ déédéé

    Ká lè máa rìn lọ́nà ìyè.

    Títí láé la ó máa sin Jèhófà,

    Àwa àti ẹgbẹ́ ará.

    Torí náà, ká máa gbéra wa ró

    Ká lè jẹ́ adúróṣinṣin.