ORIN 94
A Mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
-
1. Jèhófà Bàbá wa, jọ̀ọ́ gba ọpẹ́ wa.
A mọrírì Ìwé Mímọ́ tó o fún wa!
Òtítọ́ ni Ọ̀rọ̀ rẹ;
Ó máa ń tọ́ wa sọ́nà.
Ó dà bí ìmọ́lẹ̀, ó ń jẹ́ ká róòótọ́.
-
2. Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ máa ń wọni lọ́kàn.
Ó máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́.
Òfin rẹ ṣe kedere,
ìdájọ́ rẹ wúlò.
Àwọn ìlànà rẹ sì máa ń darí wa.
-
3. Ọ̀rọ̀ rẹ ṣàǹfààní, ó ń wọ̀ wá lọ́kàn.
Èèyàn bíi tiwa ni àwọn wòlí ì rẹ.
Jẹ́ ká tẹ̀ lápẹẹrẹ wọn;
káwa náà nígbàgbọ́.
A dúpẹ́ Jèhófà, fún ẹ̀bùn ńlá yìí!
(Tún wo Sm. 19:9; 119:16, 162; 2 Tím. 3:16; Jém. 5:17; 2 Pét. 1:21.)