ORIN 97
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ló Ń Mú Ká Wà Láàyè
-
1. A nílò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ká lè máa wà láàyè.
Oúnjẹ tara nìkan kò tó
Láti gbẹ́mìí wa ró.
Tá a bá ńgbọ́ Ọ̀rọ̀ Jèhófà,
Ayé wa yóò dára.
(ÈGBÈ)
Oúnjẹ tara nìkan kò tó
Láti gbẹ́mìí wa ró.
Ọ̀r’Ọlọ́run ṣe pàtàkì
Ká lè máa wà láàyè.
-
2. Ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́
Kọ́ wa lọ́pọ̀ ẹ̀kọ́.
Ó sọ̀rọ̀ àwọn olóòótọ́
Tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.
Àpẹẹrẹ wọn ńfún wa lókun;
Ó ńgbé ‘gbàgbọ́ wa ró.
(ÈGBÈ)
Oúnjẹ tara nìkan kò tó
Láti gbẹ́mìí wa ró.
Ọ̀r’Ọlọ́run ṣe pàtàkì
Ká lè máa wà láàyè.
-
3. Táa bá ńka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,
Yóò máa tù wá nínú.
Tí a bá kojú ìṣòro,
Ó máa ràn wá lọ́wọ́.
Ká jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Máa wà ní ọkàn wa.
(ÈGBÈ)
Oúnjẹ tara nìkan kò tó
Láti gbẹ́mìí wa ró.
Ọ̀r’Ọlọ́run ṣe pàtàkì
Ká lè máa wà láàyè.
(Tún wo Jóṣ. 1:8; Róòmù 15:4.)