Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orin 136

Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso​—Jẹ́ Kó Dé!

Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso​—Jẹ́ Kó Dé!

Wà á jáde:

(Ìṣípayá 11:15; 12:10)

  1. Jèhófà, o ti wà tipẹ́,

    Ìwọ yóò máa wà lọ.

    O gbé ọmọ rẹ gorítẹ̀ẹ́;

    O pàṣẹ kó jọba.

    A ti wá bí Ìjọba náà;

    ’Jọba rẹ̀ yóò kárí ayé.

    (ÈGBÈ)

    Ní báyìí, ìgbàlà,

    Ìjọba àtagbára dé.

    ’Jọba náà ńṣàkóso.

    Jọ̀wọ́: “Jẹ́ kó dé, Jẹ́ kó dé!”

  2. Àkókò Èṣù ti kúrú;

    A mohun téyìí jẹ́.

    À ńgbé lákòókò wàhálà,

    A ró’un táyé kò rí.

    A ti wá bí Ìjọba náà;

    ’Jọba rẹ̀ yóò kárí ayé.

    (ÈGBÈ)

    Ní báyìí, ìgbàlà,

    Ìjọba àtagbára dé.

    ’Jọba náà ńṣàkóso.

    Jọ̀wọ́: “Jẹ́ kó dé, Jẹ́ kó dé!”

  3. Àwọn áńgẹ́lì ọ̀run yọ̀

    Wọ́n sì fayọ̀ kọrin.

    Àwọn ọ̀run ti bọ́ lọ́wọ́

    Sátánì òpùrọ́.

    A ti wá bí Ìjọba náà;

    ’Jọba rẹ̀ yóò kárí ayé.

    (ÈGBÈ)

    Ní báyìí, ìgbàlà,

    Ìjọba àtagbára dé.

    ’Jọba náà ńṣàkóso.

    Jọ̀wọ́: “Jẹ́ kó dé, Jẹ́ kó dé!”