Orin 146
Èmi Lẹ Ṣe É Fún
Wà á jáde:
-
Jésù ní àgùntàn mìíràn tó ń sìn pẹ̀lú
àwọn tó f’ẹ̀mí yàn, táá jẹ́ aya rẹ̀.
Gbogbo ohun tá a bá ṣe
kára lè tù wọ́n
Jésù máa san èrè rẹ̀ fún wa pátá.
(ÈGBÈ)
“Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.
Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.
Tẹ́ ẹ bá ṣiṣẹ́ sìn wọ́n, èmi lẹ ṣe é fún.
Ẹ ti ṣe é fún wọn; ẹ ti ṣe é fún mi.
Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.”
-
“Ebi pa mí, òùngbẹ gbẹ mí, ẹ tọ́jú mi,
gbogbo ohun tí mo nílò lẹ fún mi.”
Wọ́n bi í pé: “Sọ fún wa
ìgbà wo la ṣe bẹ́ẹ̀?”
Ọba wá fèsì ó dá wọn lóhùn pé:
(ÈGBÈ)
“Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.
Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.
Tẹ́ ẹ bá ṣiṣẹ́ sìn wọ́n, èmi lẹ ṣe é fún.
Ẹ ti ṣe é fún wọn; ẹ ti ṣe é fún mi.
Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.”
-
“Ẹ j’ólóòótọ́ sí mi, iṣẹ́ rere lẹ̀ ń ṣe,
ẹ̀ ń wàásù pẹ̀l’áwọn arákùnrin mi.”
Ọba máa sọ f’áwọn
àgùntàn ọ̀tún rẹ̀:
“Ẹ jogún ayé àti ìjẹ́pípé.”
(ÈGBÈ)
“Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.
Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.
Tẹ́ ẹ bá ṣiṣẹ́ sìn wọ́n, èmi lẹ ṣe é fún.
Ẹ ti ṣe é fún wọn; ẹ ti ṣe é fún mi.
Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.”
(Tún wo Òwe 19:17; Mát. 10:40-42; 2 Tím. 1:16, 17.)