ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
2 Kọ́ríńtì 12:9—“Oore-Ọ̀fẹ́ Mi Tó fún Ọ”
“Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ, torí à ń sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.”—2 Kọ́ríńtì 12:9, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.”—2 Kọ́ríńtì 12:9, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.
Ìtumọ̀ 2 Kọ́ríńtì 12:9
Ọlọ́run sọ fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé òun máa fún un lókun láti fara da àwọn ìṣòro àti àìlera rẹ̀.
“Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ.” Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà sọ bí Ọlọ́run ṣe dá Pọ́ọ̀lù lóhùn lẹ́yìn tó gbàdúrà sí i léraléra ní pé, “inú rere mi nìkan ti tó fún ọ.” Tàbí ká sọ ọ́ lọ̀rọ̀ míì, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run nìkan ti tó fún Pọ́ọ̀lù láti kojú àwọn ìṣòro rẹ̀. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” tàbí “oore-ọ̀fẹ́” túmọ̀ sí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ téèyàn ò lẹ́tọ̀ọ́ sí àmọ́ tí Ọlọ́run fúnni tọkàntọkàn. A rí i nínú àwọn lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ pé ó jọlá inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run lọ́pọ̀ yanturu. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù máa ń ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni tẹ́lẹ̀, Ọlọ́run fún un lókun tó nílò láti yí ìwà rẹ̀ pa dà, kó sì ran àwọn míì lọ́wọ́ láti di Kristẹni. (1 Kọ́ríńtì 15:9, 10; 1 Tímótì 1:12-14) Èyí ló jẹ́ kí ọkàn Pọ́ọ̀lù balẹ̀ pé ìṣòro yòówù kí òun kojú, Ọlọ́run máa ran òun lọ́wọ́.
“Torí à ń sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Olúwa Jèhófà a rán Pọ́ọ̀lù létí pé òun máa ń fi agbára Òun hàn, ní pàtàkì lára àwa èèyàn aláìpé àti aláìlera. (2 Kọ́ríńtì 4:7; 12:8) Jèhófà máa ń lo agbára rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lórí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n gbà pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́, tí wọ́n sì ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ran àwọn lọ́wọ́. (Éfésù 3:16; Fílípì 4:13) Lọ́nà yìí, Ọlọ́run ń fi agbára rẹ̀ hàn kedere nínú àìlera wa.
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé 2 Kọ́ríńtì 12:9
Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà kan tó ní ìmísí Ọlọ́run sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì ní nǹkan bí ọdún 55 S.K. Nínú lẹ́tà kejì tó kọ sí wọn yìí, ó ṣàlàyé pé òun ní àṣẹ láti jẹ́ àpọ́sítélì. Ohun tó mú kó kọ lẹ́tà yìí ni pé àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní olùkọ́ ń bẹnu àtẹ́ lù ú, bóyá torí ìrísí rẹ̀ tàbí bó ṣe ń sọ̀rọ̀.—2 Kọ́ríńtì 10:7-10; 11:5, 6, 13; 12:11.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń gbèjà ara ẹ̀ ó sọ pé, ì bá má ṣeé ṣe fóun láti fara da onírúurú ìṣòro tó dé bá a tàbí kóun tiẹ̀ ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun, ká ní agbára òun lòun gbára lé. (2 Kọ́ríńtì 6:4; 11:23-27; 12:12) Ní orí 12, ó fi ìṣòro kan tí ò lọ̀ bọ̀rọ̀ tó sì ń fa ìrora àti ìdààmú ọkàn bá a wé ‘ẹ̀gún kan nínú ara mi.’ (2 Kọ́ríńtì 12:7) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ò sọ ìṣòro náà, ó pinnu láti fara dá a pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.
Àwọn Kristẹni lónìí náà lè níṣòro tàbí kí wọ́n kojú inúnibíni. Àmọ́, ọkàn wọn balẹ̀ pé Ọlọ́run lè lo agbára rẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ki wọ́n lè fara da ìṣòro èyíkéyìí tó bá yọjú. Àwọn náà sì lè fi ìdánilójú sọ bíi ti Pọ́ọ̀lù pé: “Nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, ìgbà náà ni mo di alágbára.”—2 Kọ́ríńtì 12:10.
Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé 2 Kọ́ríńtì.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”