ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Míkà 6:8—“Máa Rìn ní Ìrẹ̀lẹ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run Rẹ”
“Ó ti sọ ohun tó dára fún ọ, ìwọ ọmọ aráyé. Kí sì ni Jèhófà fẹ́ kí o ṣe? Bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o mọyì jíjẹ́ adúróṣinṣin, kí o sì mọ̀wọ̀n ara rẹ bí o ṣe ń bá Ọlọ́run rẹ rìn!”—Míkà 6:8, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“A ti fi ohun ohun tí ó dára hàn ọ́, ìwọ eniyan. Kí ni OLUWA fẹ́ kí o ṣe, ju pé kí o jẹ́ olótìítọ́ lọ, kí o máa ṣàánú eniyan, kí o sì máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹlu Ọlọrun rẹ?”—Míkà 6:8, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.
Ìtumọ̀ Míkà 6:8
Wòlíì Míkà sọ pé kò nira jù láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà a Ọlọ́run. (1 Jòhánù 5:3) Ẹsẹ Bíbélì yìí fi gbólóhùn mẹ́ta péré ṣàkópọ̀ ohun tí Ọlọ́run retí pé ká máa ṣe. Méjì àkọ́kọ́ dá lé àjọṣe wa pẹ̀lú ọmọnìkejì wa, ìkẹta sì dá lé àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run.
“Ṣe ìdájọ́ òdodo.” Ọlọ́run retí pé kí àwọn tó ń sin òun máa ṣe ohun tó tọ́ àtèyí tó yẹ. Èyí gba pé kí ohun tí wọ́n bá ń rò àtohun tí wọ́n bá ń ṣe bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Diutarónómì 32:4) Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń pa òfin Ọlọ́run mọ́ máa ń sapá gan-an láti jẹ́ olóòótọ́ sí gbogbo èèyàn, wọn kì í sì í ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni láìka ibi tó ti wá sí, orílẹ̀-èdè rẹ̀ tàbí ipò tó wà láwùjọ.—Léfítíkù 19:15; Àìsáyà 1:17; Hébérù 13:18.
“Mọyì jíjẹ́ adúróṣinṣin.” A tún lè túmọ̀ gbólóhùn yìí sí “fẹ́ràn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.” (Míkà 6:8, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Nínú èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “adúróṣinṣin” kọjá kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì, ó kan kéèyàn máa ṣe oore, kó sì máa ṣàánú àwọn míì, kódà lọ́nà tó tún ju bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa ṣe. Ọlọ́run fẹ́ káwọn tó bá ń ṣe ìfẹ́ òun máa ṣoore, kí wọ́n sì máa ṣàánú àwọn èèyàn, ó sì tún fẹ́ kí wọ́n mọyì àwọn ìwà dáadáa yìí. Tó fi hàn pé ní ti àwọn tó ń sin Ọlọ́run, ó yẹ kó máa yá wọn lára láti ran àwọn míì lọ́wọ́, pàápàá àwọn tó aláìní. Ó ṣe tán, tá a bá ń fúnni, a máa ń láyọ̀.—Ìṣe 20:35.
“Mọ̀wọ̀n ara rẹ bí o ṣe ń bá Ọlọ́run rẹ rìn.” Nínú Bíbélì, láti “rìn” lè túmọ̀ sí “kéèyàn máa tọ ọ̀nà kan láti ṣe ohun kan.” Ẹnì kan lè máa bá Ọlọ́run rìn tó bá ń tọ ọ̀nà ìgbésí ayé tó bá ìfẹ́ Rẹ̀ mu. Àpẹẹrẹ tó dáa ni Nóà. Ó “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn” torí pé ó jẹ́ olóòótọ́ lójú Ọlọ́run, ó sì “fi hàn pé òun jẹ́ aláìlẹ́bi láàárín àwọn tí wọ́n jọ gbé láyé.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:9) Lóde òní, àwa náà ‘ń bá Ọlọ́run rìn’ tá a bá ń fi àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò nínú ayé wa. Ìyẹn máa mú ká gbà pé ó níbi tágbára wa mọ àti pé Ọlọ́run la gbára lé nínú ohun gbogbo.—Jòhánù 17:3; Ìṣe 17:28; Ìfihàn 4:11.
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Míkà 6:8
Wòlíì ni Míkà lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Lásìkò yẹn, ìbọ̀rìṣà, jìbìtì àti fífi ọwọ́ ọlá gbáni lójú ló kún ilẹ̀ náà. (Míkà 1:7; 3:1-3, 9-11; 6:10-12) Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni kò ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, bó ṣe wà nínú Òfin tí Ọlọ́run fún Mósè, ìyẹn Òfin Mósè. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ọ̀pọ̀ ni èrò wọn kò tọ̀nà torí wọ́n rò pé Ọlọ́run ò ní bínú sáwọn táwọn bá ṣáà ti ń ṣèjọsìn táwọn sì ń rúbọ.—Òwe 21:3; Hósíà 6:6; Míkà 6:6, 7.
Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Míkà gbé láyé, Jésù tún tẹnu mọ́ ọn pé àwọn tó ní ìfẹ́, tí wọ́n ń ṣèdájọ́ òdodo àti àánú ni inú Baba òun dùn sí, àmọ́ ó kórìíra àwọn tó bá ń ṣe ojú ayé káwọn míì lè rò pé wọ́n ń sin Ọlọ́run. (Mátíù 9:13; 22:37-39; 23:23) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ káwọn tó ń sìn ín lóde òní máa ṣe.
Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Míkà.
a Lédè Yorùbá, Jèhófà ni ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù—ìyẹn lẹ́tà mẹ́rin náà יהוה (YHWH), tí wọ́n tún máa ń pè ní Tetragrammaton lédè Gẹ̀ẹ́sì. “OLÚWA” ni wọ́n pe orúkọ yìí nínú ẹsẹ Bíbélì yìí nínú Bibeli Ìròyìn Ayọ̀. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Jèhófà àti ìdí táwọn Bíbélì kan ò fi lo orúkọ náà, wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ta Ni Jèhófà?”