ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Àìsáyà 26:3—“Ìwọ Yóò Pa Á Mọ́ Ní Àlàáfíà Pípé Ọkàn Ẹni Tí Ó Dúró Ṣinṣin”
“O máa dáàbò bo àwọn tó gbára lé ọ pátápátá; o máa fún wọn ní àlàáfíà tí kò lópin, torí pé ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé.”—Àìsáyà 26:3, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pipe ọkàn ẹni tí ó dúróṣinṣin, nítorí ó gbẹ́kẹ̀ lé ọ.”—Àìsáyà 26:3, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.
Ìtumọ̀ Àìsáyà 26:3
Àwọn ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí wòlíì Àìsáyà sọ fi hàn pé Ọlọ́run máa ń dáàbò bo àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá. Ó máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti àlàáfíà.
“O máa dáàbò bo àwọn tó gbára lé ọ pátápátá.” Ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí àwọn tí wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà a pátápátá. Àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run gbà pé òun nìkan ló lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í gbára lé òye tara wọn tí wọ́n bá fẹ́ ṣèpinnu, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n máa ń jẹ́ kí èrò Ọlọ́run darí gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. (Òwe 3:5,6) Tí wọ́n bá ń ka Bíbélì, wọ̀n máa ń ronú jinlẹ̀ kí wọ́n lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́. (Sáàmù 1:2; 119:15) Tí ìṣòro bá sì dé, wọ́n máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. (Sáàmù 37:5; 55:22) Tí wọ́n bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ó ń fi hàn pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tó máa fún wọn ní àlàáfíà tòótọ́.
“O máa fún wọn ní àlàáfíà tí kò lópin.” Nínú èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ náà “àlàáfíà” máa ń fara hàn lẹ́ẹ̀mejì fún ìtẹnumọ́; fún ìdí yìí, ká lè tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ náà, á dáa ká lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “àlàáfíà tí kò lópin,” “àlàáfíà tí kò lábàwọ́n,” tàbí “àlàáfíà tó pé.” Ní ṣókí, àwọn tó bá fi gbogbo ọkàn wọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà máa ń gbádùn àlààfíà, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀ kódà tí wọ́n bá ń kojú ìsòro. (Sáàmù 112:7; 119:165) Torí náà, àwọn tó bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà tí wọ́n sì ń sapá láti ṣe ohun tó ń múnú ẹ̀ dùn ló máa ń ní irú àlàáfíà yìí.—Òwe 3:32; Àìsáyà 48:18.
Ọ̀rọ̀ náà “àlàáfíà tí kò lópin” kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run máa mú gbogbo ìṣòro àwọn tó ń sìn ín kúrò, kí wọ́n má bàá máa ṣàníyàn mọ́. (1 Sámúẹ́lì 1:6,7; Jóòbù 6:1,2; Sáàmù 31:9) Dípò bẹ́ẹ̀, ó máa fún wọn lókun kí wọ́n lè fara dà á. (Àìsáyà 41:10, 13) Ó máa ń dáhùn àdúrà wọn, ó ń fún wọn lọ́gbọ́n àti okun tí wọ́n nílò, ó sì máa ń tù wọ́n nínú. (Sáàmù 94:19; Òwe 2:6; Àìsáyà 40:29) Àwọn nǹkan yìí máa ń jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀ láìka àwọn ìṣòro tó le tí wọ́n ń báyí.—Fílípì 4:6, 7.
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Àìsáyà 26:3
Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ Ṣ.S.K ni wòlíì Àìsáyà gbé láyé. Lákòókò yẹn, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù ni ò fòótọ́ sin Jéhòfá. Torí èyí, Jèhófà fàyè gbà á pé káwọn ọ̀tá pa Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú wọn run lọ́dún 607 Ṣ.S.K.
Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún kan ọdún ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù ni Àìsáyà ti kọ orin tó fí sọ àsọtẹ́lẹ̀ láti fi yin Jèhófà bó ṣe wà ní orí kẹrìndínlọ́gbọ̀n (26). (Àìsáyà 26:1-6) Orin yìí ṣàpèjúwe bí ìlú kan ní ilẹ̀ Júdà, ìyẹn Jerúsálẹ́mù ṣe máa pa dà bọ̀ sípò lọ́jọ́ iwájú.
Lẹ́yìn ọdún 537 Ṣ.S.K, Jerúsálẹ́mù pa dà bọ̀ sípò, ó wá ṣeé ṣe fáwọn àṣẹ́kù Júù olóòótọ́ tó pa dà sí Jerúsálẹ́mù láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn kí wọ́n sì sọ pé: “A ní ìlú tó lágbára.” (Àìsáyà 26:1) Àmọ́ o, kí ì ṣe àwọn ògiri ìlú náà ló jẹ́ kó lágbára. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí Jèhófà ṣe ń bójú tó wọn tó sì ń dáàbò bò wọ́n ló jẹ́ kí ìlú náà lágbára.—Àìsáyà 26:2.
Bó sì ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Àwọn tó fi gbogbo ọkàn wọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà máa ń ní àlàáfíà torí wọ́n ti fi í ṣe “Àpáta,” tàbí ibi ààbò wọn.— Àìsáyà 26:4.
Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Àìsáyà.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta ni Jèhófà?”