Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Àìsáyà 40:31—“Àwọn Tó Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Máa Jèrè Okun Pa Dà”

Àìsáyà 40:31—“Àwọn Tó Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Máa Jèrè Okun Pa Dà”

 “Àmọ́ àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà máa jèrè okun pa dà. Wọ́n máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè réré bí ẹyẹ idì. Wọ́n máa sáré, okun ò ní tán nínú wọn; Wọ́n máa rìn, kò sì ní rẹ̀ wọ́n.”—Àìsáyà 40:31, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA yóò sọ agbára wọn di ọ̀tun. Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì; wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn, wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.”—Àìsáyà 40:31, Bíbélì Mímọ́.

Ìtumọ̀ Àìsáyà 40:31

 Jèhófà a Ọlọ́run fi dá àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ lójú pé òun máa fún wọn lókun kí wọ́n lè borí tàbí fara da ìṣòro èyíkéyìí tí wọ́n bá kojú.

 “Àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà máa jèrè okun pa dà.” Àwọn tó ní ìrètí tàbí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run gbà pé, ó ní agbára láti ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì múra tán láti fún wọn lókun tí wọ́n nílò. (Òwe 3:5, 6) Ọ̀nà míì tí Ọlọ́run gbà ń fún àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ lágbára jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ tàbí agbára ìṣiṣẹ́ rẹ̀.—Lúùkù 11:13.

 “Wọ́n máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè réré bí ẹyẹ idì.” Àpèjúwe tí ẹsẹ Bíbélì yìí lò jẹ́ ká rí bí agbára Ọlọ́run ṣe máa ń ṣiṣẹ́ lára wa. Ẹyẹ idì máa ń gbára lé afẹ́fẹ́ olóoru tó wà lójú sánmà láti fò lọ sókè réré. Tí ẹyẹ idì bá ti dé ibi tí afẹ́fẹ́ tó móoru wà, á máa fò yípo, afẹ́fẹ́ náà á sì máa gbé e lọ sókè. Á tún wá bọ́ sínú afẹ́fẹ́ míì tó móoru ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, á sì máa fò yípo níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí, ìwọ̀nba agbára díẹ̀ lá máa lò bó ṣe ń fò lọ síbi tó fẹ́ lọ.

 “Wọ́n máa sáré, okun ò ní tán nínú wọn.” Àwọn ìṣòro ìgbésí ayé lè tán wa lókun, ká sì rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ agbára tí Ọlọ́run ń fún wa á jẹ́ ká lè máa fara dà á lọ. Ó tún lè fún wa lókun láti ṣe ohun tó tọ́ láìka bó ti wù kó le tó. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà fara da àwọn ìṣòro tó le gan-an, ó sọ pé: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”—Fílípì 4:13.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáajú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Àìsáyà 40:31

 Ọlọ́run mí sí wòlíì Àìsáyà láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ yìí wà fún, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn Júù ni Jèhófà ń fọ̀rọ̀ yìí tù nínú tóri pé wọ́n máa tó lọ sóko ẹrú ní Bábílónì fún àádọ́rin (70) ọdún. Àwọn Júù rí bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe ṣẹ nígbà tí wọ́n pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn láti ìgbèkùn. (Àìsáyà 40:1-3) Ọlọ́run fún wọn lókun láti rin ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn tó sì léwu b láti Bábílónì sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni.—Àìsáyà 40:29.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.

b Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600) kìlómítà làwọn Júù tó pa dà láti ìgbèkùn Bábílónì rìn kí wọ́n tó dé ìlú ìbílẹ̀ wọn.