Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Jeremáyà 33:3—“Ké Pè Mí, Màá sì Dá Ọ Lóhùn”

Jeremáyà 33:3—“Ké Pè Mí, Màá sì Dá Ọ Lóhùn”

 “Ké pè mí, màá sì dá ọ lóhùn, mo ṣe tán láti sọ nípa àwọn ohun ńlá tí kò ṣeé lóye fún ọ, àwọn ohun tí ìwọ kò tíì mọ̀.”​—Jeremáyà 33:3, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Pè mí, èmi ó sì dá ọ lóhùn, èmi ó sì sọ ohun alágbára ńlá àti ọ̀pọ̀ ohun tí kò ṣe é wádìí tí ìwọ kò mọ̀ fún ọ.”​—Jeremáyà 33:3, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

Ìtumọ̀ Jeremáyà 33:3

 Ọlọ́run lo àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí láti pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n gbàdúrà sí òun. Àwọn tó bá gbọ́ ohun tí Ọlọ́run sọ yìí, tí wọ́n sì ṣe tán láti gbàdúrà sí i ló máa jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

 “Ké pè mí, màá sì dá ọ lóhùn.” Ọ̀rọ̀ náà “ké pè mí” kò túmọ̀ sí pé kèèyàn kàn máa pe orúkọ Ọlọ́run tàbí pariwo orúkọ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ká máa gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn wá lọ́wọ́ kó sì tọ́ wa sọ́nà.​—Sáàmù 4:1; Jeremáyà 29:12.

 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Ọlọ́run ń bá sọ ọ̀rọ̀ yìí. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti kọ Ọlọrun sílẹ̀, àwọn ọmọ ogun Bábílónì sì ń halẹ̀ mọ́ wọn. (Jeremáyà 32:1, 2) Jèhófà a wá gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níyànjú pé kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ òun, kí wọ́n sì gbàdúrà sí òun.

 “Màá sì. . . sọ nípa àwọn ohun ńlá tí kò ṣeé lóye fún ọ, àwọn ohun tí ìwọ kò tíì mọ̀.” Àwọn ohun “tí kò ṣeé lóye” (tàbí, kọjá òye) ni Ọlọ́run ṣèlérí pé ohun máa sọ fún wọn. Torí pé, àwa èèyàn ò lè lóye ẹ̀ láé láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Nígbà míì “àwọn ohun tí kò ṣeé lóye” la tún lè tú sí “àwọn ohun tó fara sin.”

 Àwọn “ohun tó fara sin” wo ni Ọlọ́run fẹ́ sọ? Àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni, ìyẹn bí Jerúsálẹ́mù ṣe máa pa run tó sì máa dahoro àti bí wọ́n á ṣe tún un kọ́ táwọn èèyàn á sì máa gbé inú rẹ̀. (Jeremáyà 30:1-3; 33:4, 7, 8) Bákan náà, Ọlọ́run tún ṣèlérí pé gbogbo àwọn tó ń jósìn òun kò ní pa run.​—Jeremáyà 32:36-38.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Jeremáyà 33:3

 Ọdún 608 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wòlíì Jeremáyà, ìyẹn ọdún kẹwàá ìṣàkóso Ọba Sedekáyà. Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa pa Jerúsálẹ́mù run, wọ́n á sì mú Sedekáyà lẹ́rú. Torí pé ọba ò fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ fún un, ó ní kí wọ́n fi Jeremáyà sínú àhámọ́.​—Jeremáyà 32:1-5; 33:1; 37:21.

 Àsìkò tí àwọn nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀ ni Ọlọ́run rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣe ohun tó wà ní Jeremáyà 33:3. Àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé, Ọba Sedekáyà àti ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn náà fàáké kọ́rí, wọn ò jáwọ́ nínú ìwà àìṣòótọ́ wọn. (Jeremáyà 7:26; 25:4) Wọn ò gbàdúrà sí Ọlọ́run láti béèrè fún ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Lẹ́yìn ọdún kan, wọ́n gba ìjọba lọ́wọ́ Sedekáyà, wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run, ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó yè bọ́ ni wọ́n sì kó lẹ́rú lọ sí Bábílónì.​—Jeremáyà 39:1-7.

 Ọ̀rọ̀ tó wà ní Jeremáyà 33:3 rán wa létí lónìí pé Ọlọ́run lè jẹ́ ká ni “ìmọ̀ tó péye nípa ìfẹ́ [rẹ̀],” kó sì jẹ́ kí àwọn tó ń gbàdúrà sí i tí wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀.” (Kólósè 1:9; 1 Kọ́ríńtì 2:10) Lára àwọn ohun ìjìnlẹ̀ yìí làwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.​—Ìfihàn 21:3, 4.

 Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Jeremáyà.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?