ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Jóṣúà 1:9—“Jẹ́ Onígboyà àti Alágbára”
“Ṣebí mo ti pàṣẹ fún ọ? Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, má sì jáyà, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí o bá lọ.”—Jóṣúà 1:9, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”—Jóṣúà 1:9, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìtumọ̀ Jóṣúà 1:9
Ọ̀rọ̀ yìí ni Jèhófà a Ọlọ́run sọ fún Jóṣúà tó ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run. Ó mú kó dá Jóṣúà lójú pé ó lè “jẹ́ onígboyà àti alágbára” láìka àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ sí. Kò sídìí fún Jóṣúà láti bẹ̀rù ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tó bá ṣe ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún un, torí pé ṣe ló máa dà bí ìgbà tí Jèhófà dúró tì í tó sì ń ràn an lọ́wọ́ kó lè ṣàṣeyọrí. Ọlọ́run wà pẹ̀lú Jóṣúà ní ti pé ó ń sọ nǹkan tó máa ṣe fún un, ó sì ń ràn án lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Báwo ni Jóṣúà ṣe lè “jẹ́ onígboyà àti alágbára”? Ó lè rí àwọn ọ̀rọ̀ tó máa fún un ní ìgboyà àti agbára nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mí sí tó wà lákọ̀ọ̀lẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Lára ẹ̀ ni “gbogbo Òfin tí Mósè ìránṣẹ́ [Jèhófà] pa láṣẹ fún [Jóṣúà].” b (Jóṣúà 1:7) Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé “kí o máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà á [“máa ṣe àṣàrò,” Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní ] tọ̀sántòru.” (Jóṣúà 1:8) Tí Jóṣúà bá ń kà á tó sì ń ṣe àṣàrò lọ́nà yìí, ó máa jẹ́ kó múra tán látọ̀kànwá láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Lẹ́yìn náà, Jóṣúà máa ní láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tó kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn ni pé kó máa “tẹ̀ lé gbogbo ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀.” Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, èyí máa jẹ́ kó lè máa hùwà ọgbọ́n, ọ̀nà rẹ̀ á sì yọrí sí rere. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóṣúà dojú kọ ìṣòro lọ́kan-ò-jọ̀kan, síbẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀ yọrí sí rere, ó sì fi tọkàntọkan sin Jèhófà.—Jóṣúà 23:14; 24:15.
Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Jóṣúà ṣì ń fún wa níṣìírí lóde òní. Ó jẹ́ ká mọ bí ọ̀rọ̀ àwọn tó ń sin Jèhófà ṣe ká a lára tó, pàápàá nígbà tí wọ́n bá dojú kọ ìṣòro. Ó fẹ́ kí ọ̀nà wọn yọrí sí rere bíi ti Jóṣúà! Bíi Jóṣúà, àwọn náà lè “jẹ́ onígboyà àti alágbára” tí wọ́n bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn Bíbélì, tí wọ́n ń ṣe àṣàrò, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà rẹ̀.
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Jóṣúà 1:9
Lẹ́yìn tí Mósè kú, Jèhófà ní kí Jóṣúà di aṣáájú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (Jóṣúà 1:1, 2) Lákòòkò yẹn, díẹ̀ ló kù káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, ìyẹn ilẹ̀ Kénáánì. Àmọ́, wọ́n máa kojú àwọn ọ̀tá tó lágbára gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Jóṣúà ní láti bá àwọn ọmọ Kénáánì tó roro gan-an jagun. c (Diutarónómì 9:5; 20:17, 18) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọmọ Kénáánì tún pọ̀ gàn-an, wọ́n sì ní àwọn ohun ìjà ogun ju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. (Jóṣúà 9:1, 2; 17:18) Àmọ́ Jóṣúà lo ìgboyà, ó ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà ní kó ṣe. Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú rẹ̀, torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun púpọ̀ lára àwọn ọ̀tá wọn láàárín ọdún mẹ́fà péré.—Jóṣúà 21:43, 44.
a Jèhófà la máa ń pe orúkọ Ọlọ́run lédè Yorúbà, ó jẹ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ èdè Hébérù mẹ́rin yìí יהוה (YHWH), tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run. Wọ́n túmọ̀ orúkọ yìí sí “Olúwa” nínú Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB). Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i nípa Jèhófà àti ìdí tí àwọn atúmọ̀ Bíbélì kan ò fi lo orúkọ yìí, wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”
b Ó ṣée ṣé káwọn ìwé márùn-ún tí Mósè kọ, ìyẹn (Jẹ́nẹ́sísì, Ẹ́kísódù, Léfítíkù, Nọ́ńbà àti Diutarónómì), wà lára àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí tí Jóṣúà ní lọ́wọ́, tó sì tún wà nínú Bíbélì fún àwa náà lóde òní. Ìwé Jóòbù àti Sáàmù méjì náà lè wà lára ẹ̀.
c Tó o bá fẹ́ àlàyé lórí ìdí tó fi pọn dandan pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ja àwọn ogun yẹn, wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Kọjú Ìjà Sí Àwọn Ọmọ Kénáánì?” nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2010.