ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Nọ́ńbà 6:24-26—“Kí OLÚWA Bùkún Un Yín Kí Ó sì Pa Yín Mọ́”
“Kí Jèhófà bù kún ọ, kó sì pa ọ́ mọ́. Kí Jèhófà mú kí ojú rẹ̀ tàn sí ọ lára, kó sì ṣojúure sí ọ. Kí Jèhófà bojú wò ọ́, kó sì fún ọ ní àlàáfíà.”—Nọ́ńbà 6:24-26, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“Kí OLÚWA bùkún un yín kí ó sì pa yín mọ́. Kí OLÚWA kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára. Kí ó sì ṣàánú fún un yín. Kí OLÚWA bojú wò yín; kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà.”—Numeri 6:24-26, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.
Ìtumọ̀ Nọ́ńbà 6:24-26
Àwọn kan máa ń pe àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí ní ìbùkún àwọn àlùfáà tàbí ti Áárónì. Ìdí ni pé Áárónì ni àlùfáà àgbà àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì (Ẹ́kísódù 28:1) Àmọ́, Ọlọ́run ló sọ ọ̀rọ̀ yìí. (Nọ́ńbà 6:22, 23) Torí ó sọ fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Bí ẹ ó ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí.’ ” Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run sọ ohun tó wà nínú Nọ́ńbà 6:24-26. Àwọn àlùfáà tó jẹ́ olóòótọ́ máa ń pa àṣẹ Ọlọ́run yìí mọ́. Wọ́n tún máa ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run ìyẹn Jèhófà. a Ẹsẹ 27 kà pé: “Kí wọ́n [ìyẹn àwọn àlùfáà] sì fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí n lè bù kún wọn.”
“Kí Jèhófà bù kún ọ, kó sì pa ọ́ mọ́.” Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ ní ti pé ó máa ń dáàbò bò wọ́n, ó ń tọ́ wọn sọ́nà, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n ṣàṣeyọrí. (Òwe 10:22) Ọ̀rọ̀ náà “ọ” tó fara hàn léraléra nínú Nọ́ńbà 6:24-26 ń tọ́ka sí ẹnì kan ṣoṣo. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lápapọ̀ nìkan ni Ọlọ́run máa bù kún, àmọ́ ó tún máa bù kún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.
“Kí Jèhófà mú kí ojú rẹ̀ tàn sí ọ lára, kó sì ṣojúure sí ọ.” Tá a bá ní kí Ọlọ́run “mú kí ojú rẹ̀ tàn” sára ẹnì kan, ohun tó túmọ̀ sí ni pé kó ṣojúure sí ẹni náà, kó sì tẹ́wọ́ gbà á. b Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì tiẹ̀ tú ọ̀rọ̀ yìí sí: “Kí inú OLÚWA dùn sí ọ.” (Nọ́ńbà 6:25, New International Reader’s Version) Ọ̀nà tí Jèhófà máa ń gbà ṣojúure sáwọn èèyàn rẹ̀ ni pé ó máa ń ṣàánú wọn, ó sì máa ń fi inúure hàn sí wọn.—Àìsáyà 30:18.
“Kí Jèhófà c bojú wò ọ́, kó sì fún ọ ní àlàáfíà.” Jèhófà ń ‘bojú wo’ àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ ní ti pé ó ń fìfẹ́ tọ́ wọn sọ́nà, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n ní àlàáfíà. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ sọ pé, “ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí àlàáfíà (shalom) kò kàn túmọ̀ sí pé kéèyàn wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn míì nìkan, dípò bẹ́ẹ̀ ohun tó túmọ̀ sí ni pé inú ẹni náà ń dùn, ara ẹ̀ sì yá gágá torí pé ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.”
Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá máa rí ìbùkún tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí gbà, wọ́n gbọ́dọ̀ máa pa àwọn òfin Jèhófà mọ́. (Léfítíkù 26:3-6, 9) Láwọn àsìkò tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ń mú ìlérí yìí ṣẹ. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn nígbà táwọn ọba bíi Sólómọ́nì àti Hẹsikáyà ṣàkóso.—1 Àwọn Ọba 4:20, 25; 2 Kíróníkà 31:9, 10.
Tá a bá fẹ́ gbàdúrà tàbí fún àwọn Kristẹni bíi tiwa níṣìírí, a lè lò lára àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí dípò ká sọ ọ́ di àdúrà àkọ́sórí. (1 Tẹsalóníkà 5:11, 25) Jèhófà kì í yí pa dà. Gbogbo ìgbà ló ṣe tán láti bù kún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń ní àlàáfíà bí wọ́n ṣe mọ̀ pé ‘ojú’ Jèhófà ń tàn sára wọn.
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Nọ́ńbà 6:24-26
Orí mẹ́wàá àkọ́kọ́ nínú ìwé Nọ́ńbà ṣàkọsílẹ̀ ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítòsí Òkè Sínáì nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. Ní nǹkan bí ọdún kan tí wọ́n fi wà ní ibùdó náà, Jèhófà sọ àwọn èèyàn náà di orílẹ̀-èdè kan, ó wá fún wọn láwọn òfin tó para pọ̀ di Májẹ̀mú Òfin.
Jèhófà sọ fún Mósè pé kó sọ fún Áárónì àtàwọn ọmọ ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ àlùfáà bí wọ́n á ṣe máa súre fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Nọ́ńbà 6:22, 23) Lẹ́yìn náà, Áárónì àtàwọn ọmọ ẹ̀ lo àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ní Nọ́ńbà 6:24-26 láti súre fún orílẹ̀-èdè náà. Látìgbà yẹn ló ti di àṣà àwọn àlùfáà láti máa lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn tí wọ́n bá rúbọ tán lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan nínú tẹ́ńpìlì.
Wo fídíò kékeré yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Nọ́ńbà.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run bó ṣe wà ní èdè Hébérù. Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tí ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ṣe fi Olúwa rọ́pò orúkọ Ọlọ́run, ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”
b Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tí kò tọ́ Bíbélì sọ pé Jèhófà fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún wọn.—Àìsáyà 59:2; Míkà 3:4.
c Bó ṣe wà nínú Bíbélì NIV tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́, bí wọ́n ṣe lo orúkọ Ọlọ́run léraléra nínú àwọn ẹsẹ yìí “jẹ́ ká rí bí orúkọ náà ti ṣe pàtàkì tó bó ṣe wà ní [ẹsẹ 27].” Àmọ́, àwọn kan sọ pé bí orúkọ Ọlọ́run ṣe fara hàn nígbà mẹ́tà nínú àwọn ẹsẹ yìí fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan. Àmọ́, kì í ṣe bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé “àwọn àlùfáà tó ń súre àtàwọn èèyàn tí wọ́n ń súre fún ò ní jẹ́ gbà láé pé bí wọ́n ṣe lo orúkọ Ọlọ́run lẹ́ẹ̀mẹ́ta túmọ̀ sí pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí wọ́n ṣe tẹnu mọ́ orúkọ Ọlọ́run yìí túmọ̀ sí pé ìbùkún náà máa rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.” (The Pulpit Commentary, ìdìpọ̀ kejì ojú ìwé 52) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Mẹ́talọ́kan ni Ọlọ́run?”