ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Òwe 16:3—“Fi Gbogbo Àdáwọ́lé Rẹ lé OLUWA Lọ́wọ́”
“Fi gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lé Jèhófà lọ́wọ́, ohun tí o fẹ́ ṣe á sì yọrí sí rere.”—Òwe 16:3, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“Fi gbogbo àdáwọ́lé rẹ lé OLUWA lọ́wọ́, èrò ọkàn rẹ yóo sì yọrí sí rere.”—Òwe 16:3, Ìròyìn Ayọ̀.
Ìtumọ̀ Òwe 16:3
Ẹsẹ Bíbélì yìí ń jẹ́ kó dá àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ lójú pé tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ lé e, tí wọ́n sì ń wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe, wọ́n máa ṣàṣeyọrí.
“Fi gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lé Jèhófà lọ́wọ́.” Àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà a máa ń gbà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé kó tọ́ àwọn sọ́nà kí wọ́n tó ṣe ìpinnu èyíkéyìí. (Jémíìsì 1:5) Ìdí ni pé, òní la rí kò sẹ́ni tó mọ̀la, ìyẹn ni pé kò sẹ́ni tó mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí òun nígbàkigbà. (Oníwàásù 9:11; Jémíìsì 4:13-15) Yàtọ̀ síyẹn, ó níbi tí ọgbọ́n àwa èèyàn mọ. Ìdí nìyẹn, tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi máa ń fi ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe lé Ọlọ́run lọ́wọ́. Wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa gbígbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó tọ́ àwọn sọ́nà, wọ́n sì máa ń ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mú bó ṣe wà nínú Bíbélì tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Òwe 3:5, 6; 2 Tímótì 3:16, 17.
Gbólóhùn náà “fi gbogbo àdáwọ́lé rẹ lé OLUWA b lọ́wọ́” túmọ̀ sí “yí ẹrù rẹ lọ sọ́dọ̀ OLÚWA.” Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ yìí ṣàpèjúwe “ọkùnrin kan (tó) gbé ẹrù tó wúwo kúrò lẹ́yìn ara rẹ̀, tó sì gbé e fún ẹlòmíì tó lágbára jù ú lọ láti bá a gbé e.” Àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ Ọlọ́run tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ gbà pé ó máa ràn àwọn lọ́wọ́ àti pé ó máa fún àwọn lókun.—Sáàmù 37:5; 55:22.
Gbólóhùn náà “gbogbo ohun tí o bá ń ṣe” kò túmọ̀ sí pé gbogbo ohun téèyàn bá fẹ́ ṣe ni Ọlọ́run máa bù kún tàbí fọwọ́ sí. Kéèyàn tó lè rí ìbùkún Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, kí ohun náà sì bá ìfẹ́ Ọlọ́run mú. (Sáàmù 127:1; 1 Jòhánù 5:14) Ọlọ́run kì í bù kún àwọn aláìgbọràn. Kódà, “ó ń sọ èrò àwọn ẹni burúkú dòfo.” (Sáàmù 146:9) Lọ́nà kan náà, ó ń ran àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì.—Sáàmù 37:23.
“Ohun tí o fẹ́ ṣe á sì yọrí sí rere.” Àwọn Bíbélì kan tú ọ̀rọ̀ yìí sí “a o si fi idi ìro-inu rẹ kalẹ.” Nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù táwọn kan ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé, ọ̀rọ̀ náà tí wọ́n tú sí ‘fi ìdí kalẹ̀’ ń gbé èrò pé kéèyàn fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀, ó sì lè tọ́ka sì àwọn ohun tí Ọlọ́run dá tó fìdí múlẹ̀. (Òwe 3:19; Jeremáyà 10:12) Bákan náà, Ọlọ́run máa mú èrò ọkàn àwọn tó ń ṣe ohun tó tọ́ lójú rẹ̀ ṣẹ, ó sì máa jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀ kí wọ́n sì láyọ̀.—Sáàmù 20:4; Òwe 12:3.
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Òwe 16:3
Ọba Sólómọ́nì ló kọ òwe yìí, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé òun ló kọ èyí tó pọ̀ jù nínú ìwé Òwe. Torí pé Ọlọ́run fún un ní ọgbọ́n tó pọ̀ gan-an, èyí ló jẹ́ kó lè kọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún òwe.—1 Àwọn Ọba 4:29, 32; 10:23, 24.
Ní orí kẹrìndínlógún (16), Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Jèhófà nítorí ọgbọ́n Rẹ̀ tí ò láfiwé àti bó ṣe kórìíra àwọn tó jẹ́ agbéraga. (Òwe 16:1-5) Orí yìí jẹ́ kí àwọn tó ń ka ìwé Òwe rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé tí wọ́n bá fẹ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. (Òwe 16:3, 6-8, 18-23) Léraléra ni òtítọ́ yìí fara hàn nínú Bíbélì.—Sáàmù 1:1-3; Àìsáyà 26:3; Jeremáyà 17:7, 8; 1 Jòhánù 3:22.
Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó wà nínú ìwé Òwe wo fídíò kékeré yìí.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”
b Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀ lo “OLÚWA” (ìyẹn OLÚWA onílẹ́tà gàdàgbà) dípò orúkọ Ọlọ́run ìyẹn Jèhófà. Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tí ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì fi lo OLÚWA dípò Jèhófà, wo àpilẹ̀kọ tó wà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí “Àìsáyà 42:8—“Èmi ni OLÚWA.””