Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Òwe 17:17—“Ọ̀rẹ́ A Máa Fẹ́ni Nígbà Gbogbo”

Òwe 17:17—“Ọ̀rẹ́ A Máa Fẹ́ni Nígbà Gbogbo”

“Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”​—Òwe 17:17, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

“Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.”​—Òwe 17:17, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

Ìtumọ̀ Òwe 17:17

 Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ màa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni, wọ́n sì ṣe é fọkàn tán. Ṣe ni wọ́n dà bí ọmọ ìyá tó máa ń dúró tini pàápàá nígbà ìṣòro.

 “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo.” Lédè míì, a lè sọ pé “gbogbo ìgbà làwọn ọ̀rẹ́ máa ń fìfẹ́ hàn.” Ọ̀rọ̀ Hébérù náà “ìfẹ́” tá a lò nínú gbólóhùn yìí kọjá bí ọ̀rọ̀ ẹnì kan ṣe rí lára wa, kàkà bẹ́ẹ́ ṣe ló jẹ́ ohun tá à ń ṣe fún ẹnì kan torí pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ látọkàn wá. (1 Kọ́ríńtì 13:4-7) Irú àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́nà yìí máa ń dúró ti ara wọn láìka ìṣòro èyíkèyìí tí wọ́n bá ní sí. Kódà wọ́n ṣì máa ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn tí wọn ò bá tiẹ̀ gbọ́ ara wọn yé tàbí tí wọ́n láwọn ìṣòro míì. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń dárí ji ara wọn fàlàlà. (Òwe 10:12) Kò tán síbè o, ẹni tó bá jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ kì í jowú tàbí ṣe ìlara tí nǹkan bá ń lọ dáadáa fún ẹnì kejì ẹ̀, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe lá máa bá a yọ̀.​—Róòmù 12:15.

 “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ . . . jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.” Òwe yìí fi ọ̀rẹ́ tòótọ́ wé ọmọ ìyá torí pé àwọn ọmọ ìyá máa ń sún mọ́ ara wọn gan-an. Torí náà, tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran ọ̀rẹ́ wa lọ́wọ́ nígbà ìṣòro, ṣe la máa dà bí ọmọ ìyá. Yàtọ̀ síyẹn, ìfẹ́ táwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń ní kì í dín kù tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín wọn. Kàkà bẹ́ẹ́, okùn ọ̀rẹ́ wọn máa ń lágbára sí i torí ìfẹ́ wọn dénú, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú atí Èyí Tó Tẹ̀ Lé Òwe 17:17

 Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó ṣe ṣókí, tó sì ń múni ronú jinlè ló wà nínú ìwé Òwe. Ọba Sólómọ́nì ló kọ èyí tó pọ̀ jù nínú ìwé Òwe. Bí wọ́n ṣe máa ń kọ ewì ní èdè Hébérù náà ni wọ́n kọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Òwe. Dípò kí wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ tó dún bákan náà, àwon ọ̀rọ̀ tó jọ ara wọn tàbí èyí tó jẹ́ òdì kejì ohun tí wọ́n sọ ni wọ́n lò. Òwe 17:17 jẹ́ àpẹẹre ọ̀rọ̀ ewì tó jọra wọn, apá kejì ẹsẹ yìí ṣe àlàyé tó túbọ̀ mú kí apá àkọ́kọ́ jókòó dáadáa. Òwe 18:24 jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀ éwì tí apá kejì rẹ̀ jẹ́ òdì kejì ohun tó wà ní apá àkọ́kọ́. Ẹsẹ yẹn sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà tí wọ́n ṣe tán láti ṣe ara wọn níkà, àmọ́ ọ̀rẹ́ kan wà tó ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ.”

 Nígbà tí Sólómọ́nì ń kọ Òwe 17:17, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín Dáfídì bàbá ẹ̀ àti Jónátánì tó jẹ́ ọmọ Sọ́ọ̀lù ló ní lọ́kàn. (1 Sámúẹ́lì 13:16; 18:1; 19:1-3; 20:30-34, 41, 42; 23:16-18) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì àti Jónátánì kì í ṣe ọmọ ìyá kan náà, wọ́n sún mọ́ra ju ọmọ ìyá lọ. Kódà Jónátánì tiẹ̀ fi ẹ̀mí ara ẹ̀ wewu nítorí ọ̀rẹ́ rẹ̀. a

Bí Wọ́n Ṣe Túmọ̀ Òwe 17:17 Nínú Àwọn Ìtumọ̀ Bíbélì Míì

 “Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, ṣugbọn a bí arakunrin láti dúró tini ní ìgbà ìpọ́njú.”​—Yoruba Bible.

 “Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.”​—Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

 Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Òwe.

a Ka àpilẹ̀kọ náà “Wọ́n Di Ọ̀rẹ́ Tímọ́tímọ́.”