Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Òwe 22:6—“Tọ́ Ọmọdé ní Ọ̀nà Tí Yóò Tọ̀”

Òwe 22:6—“Tọ́ Ọmọdé ní Ọ̀nà Tí Yóò Tọ̀”

 “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀; kódà tó bá dàgbà, kò ní kúrò nínú rẹ̀.”​—Òwe 22:6, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.”​—Òwe 22:6, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

Ìtumọ̀ Òwe 22:6

 Àwọn òbí tó kọ́ àwọn ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ máa gbà pé ẹ̀kọ́ yìí máa ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn.

 “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀.” Ọ̀nà míì tá a tún lè túmọ̀ gbólóhùn yìí sí ni “tọ́ ọmọ rẹ sí ọ̀nà tí ó yẹ kí ó máa rìn.” Láwọn ibi tó yàtọ̀ síra nínú ìwé Òwe ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti gba àwọn òbí nímọ̀ràn pé láti kékeré ni kí wọ́n ti máa kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Òwe 19:18; 22:15; 29:15) Àmọ́, ó yẹ kí àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn dénú mọ̀ pé àwọn ọmọ náà lómìnira láti yan ohun tí wọ́n bá fẹ́. Torí náà, dípò kí wọ́n kàn máa sọ ohun tó yẹ káwọn ọmọ ṣe fún wọn, ṣe ló yẹ kí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe lè ronú torí èyí á jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ìpinnu tó dáa fúnra wọn bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Wọ́n á sì lè di ẹni tó ṣeé fọkàn tán.​—Diutarónómì 6:6, 7; Kólósè 3:21.

 Àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan sọ pé gbólóhùn náà lè túmọ̀ sí pé “kí wọ́n tọ́ ọmọ bí ìwà rẹ̀ ṣe rí” tàbí kí wọ́n tọ́ ọmọ ní ìbámu pẹ̀lú irú ẹni tó jẹ́. Ó lè dà bíi pé ìtumọ̀ yìí bọ́gbọ́n mu, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀” tọ́ka sí kéèyàn gbé ìgbésí ayé tó dáa, tó sì bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ìwé Òwe sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà méjì tí èèyàn lè tọ̀. Ó pe ọ̀nà kan ní “ọ̀nà àwọn ẹni rere,” “ọ̀nà ọgbọ́n” àti ‘ọ̀nà tó tọ́.’ (Òwe 2:20; 4:11; 23:19) Ó pe ọ̀nà kejì ni “ọ̀nà àwọn ẹni ibi,” “ọ̀nà òmùgọ̀” àti ‘ọ̀nà tí kò tọ́.’ (Òwe 4:14; 12:15; 16:29 Yoruba Bible) Torí náà, ọ̀nà ‘tó yẹ kí ọmọ kan tọ̀’ ni ‘ọ̀nà tó tọ́’ ìyẹn ọ̀nà ìyè tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wa.​—Sáàmù 119:105.

 “Kódà tó bá dàgbà, kò ní kúrò nínú rẹ̀.” Tí àwọn òbí bá ń fi ìlànà Ọlọ́run nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa hùwà kọ́ ọmọ wọn, ó dájú pé ọmọ náà ò ní kúrò ní ọ̀nà tó tọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Àmọ́, èyí ò wá túmọ̀ sí pé ọmọ tí wọ́n tọ́ dáadáa kò lè “kúrò” ní ọ̀nà tó tọ́ tàbí kó lè pa òfin Ọlọ́run tì. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹnì kan bá ń bá ẹni tó ń hùwà burúkú rìn, ó lè kúrò ní “ọ̀nà òdodo,” kó sì máa hùwà tí ò dáa. (Òwe 2:12-16; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Kódà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, òbí kan tó ti kọ́ ọmọ rẹ̀ láti máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run ti fún ọmọ náà láǹfààní láti ṣàṣeyọrí ní ìgbésí ayé.​—Òwe 2:1, 11.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Òwe 22:6

 Òwe orí 22 ní àwọn gbólóhùn ṣókí tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi ọgbọ́n Ọlọ́run sílò ní onírúurú ipò tá a bá bára wa. Àwọn gbólóhùn yìí jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà, a a sì lè ní orúkọ rere yìí tá a bá ní ìrẹ̀lẹ̀, tá a jẹ́ ọ̀làwọ́, tá a sì jẹ́ òṣìṣẹ́ kára. (Òwe 22:1, 4, 9, 29) ) Lódì kejì, àwọn ẹsẹ míì nínú orí yìí jẹ́ ká rí i pé àwọn tí kò tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn aláìní máa jìyà ohun tí wọ́n ṣe.​—Òwe 22:8, 16, 22-27.

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Òwe orí 22 kò sọ̀rọ̀ nípa ọmọ títọ́ ní tààràtà, ó sọ bá a ṣe lè gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tá a fi máa rí ojú rere Ọlọ́run, ká sì ní ayọ̀ tòótọ́. (Òwe 22:17-19) Tí àwọn òbí bá ń tọ́ àwọn ọmọ láti máa gbé irú ìgbé ayé yìí, ṣe ni wọ́n ń fi hàn pé wọ́n fẹ́ kí ìgbésí ayé àwọn ọmọ wọn nítumọ̀.​—Éfésù 6:1-3.

 Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Òwe.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?