ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Sáàmù 23:4—“Bí Mo Tilẹ̀ Ń Rìn Nínú Àfonífojì Tó Ṣókùnkùn Biribiri”
“Bí mo tilẹ̀ ń rìn nínú àfonífojì tó ṣókùnkùn biribiri, mi ò bẹ̀rù ewukéwu, nítorí o wà pẹ̀lú mi; ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.”—Sáàmù 23:4, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“Bí mo tilẹ̀ ń rìn láàrín àfonífojì òjìji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan; nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ wọ́n ń tù mí nínú.“—Sáàmù 23:4, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìtumọ̀ Sáàmù 23:4 a
Ọlọ́run máa ń dáàbò bo àwọn tó ń sìn ín, ó sì máa ń bójú tó wọn, kódà bí ipò nǹkan bá tiẹ̀ nira fún wọn. Ẹsẹ Bíbélì yìí fi bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ wé bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe máa ń bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀. b Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé bí wọ́n tilẹ̀ ń rìn nínú àfònífojì tó ṣókùnkùn biribiri, tàbí tí wọ́n dojú kọ ikú, ẹ̀rù ò ní bà wọ́n. Ọkàn wọn balẹ̀, ṣe ló dà bí i pé wọ́n ń rí Ọlọ́run lójúkojú tó sì ń dáàbò bò wọ́n.
Lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń lo ọ̀pá láti dáàbò bo àwọn àgùntàn wọn lọ́wọ́ àwọn ẹranko ẹhànnà tó fẹ́ pa wọ́n jẹ. Wọ́n tún máa ń lo ọ̀pá tó ní orí kọrọdọ láti darí àwọn àgùntàn tàbí láti fi yọ wọ́n nínú ewu. Ṣe ni Jèhófà dà bí Olùṣọ́ àgùntàn, ó nífẹ̀ẹ́, ó sì ń dáàbò bo àwọn tó ń sìn ín, kódà, ó máa ń yọ wọ́n nínú ewu. Nígbà tí nǹkan bá tiẹ̀ nira fún wọn, oríṣiríṣi ọ̀nà ni Jèhófà máa ń gbà bójú tó wọn.
Ó ń fún wọn ní ìtọ́ni, ó sì ń tù wọ́n nínú nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Róòmù 15:4.
Ó ń gbọ́ àdúrà wọn, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n ní ìbàlẹ̀ ọkàn.—Fílípì 4:6, 7.
Ó máa ń lo àwọn tí wọ́n jọ ń sìn ín láti fún wọn ní ìṣìrí.—Hébérù 10:24, 25.
Ó fi dá wọn lójú pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa lọ́jọ́ iwájú, nígbà tó bá mú gbogbo ìṣòro tó dé bá wọn báyìí kúrò.—Sáàmù 37:29; Ìfihàn 21:3-5.
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Sáàmù 23:4
Dáfídì tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ tó sì wá di ọba orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láye àtijọ́ ló kọ Sáàmù 23. (1 Sámúẹ́lì 17:34, 35; 2 Sámúẹ́lì 7:8) Níbẹ̀rẹ̀ sáàmù yìí, ó ṣàpèjúwe pé Jèhófà jẹ́ Olúṣọ́ Àgùntàn tó ń darí àwọn tó ń sìn ín, ó ń bọ́ wọn, ó sì ń tù wọ́n lára, gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ ṣé máa ń ṣe sáwọn àgùntàn rẹ̀.—Sáàmù 23:1-3.
Ní Sáàmù 23:4, nígbà tí Dáfídì ń sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe ń dáàbò bò wá, ṣe ló sọ̀rọ̀ bí ẹni tó ń rí Ọlọ́run lójúkojú, èyí jẹ́ ká rí i pé àjọṣe tímọ́tímọ́ ló wà láàárín Ọlọ́run àti Dáfídì. Ó mọ̀ pé Ọlọ́run bìkìtá nípa òun àti pé ó mọ gbogbo ìṣòro tòun ń bá yí. Ìdí nìyẹn tí Dáfídì kò fi bẹ̀rù ewu èyíkéyìí.
Ní ẹsẹ 5 àti 6 nínú ìwé Sáàmù 23 yẹn, ó yí àpèjúwe tó lò nípa olùṣọ́ àgùntàn àti àgùntàn pa dà sí ti alèjò àti ẹni tó gbàlejò. Bí ẹni tó gba àlèjò, Jèhófà ka Dáfídì sí àlejò pàtàkì. Àwọn ọ̀tá Dáfídì pàápàá kò tó bẹ́ẹ̀ láti di Dáfídì lọ́wọ́ kó má ṣe gbádùn àbòjútó Ọlọ́run. Ní ìparí sáàmù yẹn, Dáfidì sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó dáa lójú pé ire àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Ọlọ́run ní sí òun máa wà títí ọjọ́ ayé òun.
Àpèjúwe ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 23 jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kò ní yẹ̀ láéláé.—1 Pétérù 2:25.
a Nínú àwọn Bíbélì kan, inú Sáàmù 22 làwọn ọ̀rọ̀ yìí wà. Àádọ́jọ [150] ni gbogbo Sáàmù tó wà lápapọ̀, àwọn Bíbélì kan tò ó bí wọ́n ṣe tò ó nínú ìwé Másórétì lédè Hébérù, nígbà tí àwọn Bíbélì míì tò ó bí wọ́n ṣe tò ó nínú Bíbélì Greek Septuagint, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì, tí ìtumọ̀ rẹ̀ sì parí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
b Nínú Bíbélì, wọ́n sábà máa ń ṣàpèjúwe Ọlọ́run, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà pé ó jẹ́ Olùṣọ́ àgùntàn tó láájò. Àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ dà bí àgùntàn, wọ́n sì gbára lé e pé ó máa dáàbò bo àwọn, á sì tì àwọn lẹ́yìn.—Sáàmù 100:3; Aísáyà 40:10, 11; Jeremáyà 31:10; Ìsíkíẹ́lì 34:11-16.