ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Sáàmù 46:10—“Ẹ Dúró Jẹ́ẹ́, Kí Ẹ sì Mọ̀ Pé Èmi Ní Ọlọ́run”
“Ẹ túúbá, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run. A ó gbé mi ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè; a ó gbé mi ga ní ayé.”—Sáàmù 46:10, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run. A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè; a ó gbé mi ga ní ayé.”—Sáàmù 46:10, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB).
Ìtumọ̀ Sáàmù 46:10
Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èèyàn máa jọ́sìn òun, kí wọ́n sì gbà pé òun ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Gbogbo ẹni tó bá fẹ́ wà láàyè títí láé gbọ́dọ̀ gbà pé òun ni ọba aláṣẹ àti pé agbára rẹ̀ ò láfiwé.—Ìfihàn 4:11.
“Ẹ túúbá, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan lo ọ̀rọ̀ náà “ẹ dúró jẹ́ẹ́” ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí. Èyí sì ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ṣi ọ̀rọ̀ yìí lóye. Wọ́n gbà pé ohun tó túmọ̀ sí ni pé èèyàn gbọ́dọ̀ dákẹ́ nínú ìjọ. Àmọ́, ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “ẹ túúbá, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run” jẹ́ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà a Ọlọ́run fi gba gbogbo èèyàn orílẹ̀-èdè níyànjú pé kí wọ́n yéé ta ko òun, kí wọ́n sì gbà pé òun nìkan ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn.
Ohun tó fara jọ èyí náà ló wà nínú Sáàmù 2. Ọlọ́run sọ níbẹ̀ pé òun máa fìyà jẹ àwọn tó ń ta ko òun. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tó fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀, wọ́n máa ń jẹ́ kí Ọlọ́run tọ́ àwọn sọ́nà, wọ́n sì máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó fún àwọn lọ́gbọ́n àti okun. “Àwọn tó fi Í ṣe ibi ààbò” máa ń láyọ̀, ọkàn wọn sì máa ń balẹ̀ pàápàá lákòókò ìṣòro.—Sáàmù 2:9-12.
“A ó gbé mi ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè; a ó gbé mi ga ní ayé.” Láyé àtijọ́, àwọn èèyàn gbé Jèhófà Ọlọ́run ga nígbà tó fi agbára ńlá rẹ̀ dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀. (Ẹ́kísódù 15:1-3) Tó bá dọjọ́ iwájú, a máa gbé orúkọ rẹ̀ ga lọ́nà tó kàmàmà nígbà tí gbogbo aráyé bá fi ara wọn sábẹ́ àkóso rẹ̀, tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀.—Sáàmù 86:9, 10; Àìsáyà 2:11.
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Sáàmù 46:10
Ìwé kan pe Sáàmù 46 ní “orin tí wọ́n fi ń yin Ọlọ́run nítorí agbára ńlá rẹ̀ tó fi ń gba àwọn èèyàn rẹ̀ là.” Táwọn èèyàn bá ń kọ orin tó wà nínú Sáàmù 46, ṣe ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn gbà pé Jèhófà lágbára láti dáàbò bo àwọn, kó sì ran àwọn lọ́wọ́. (Sáàmù 46:1, 2) Àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ sì ń jẹ́ kó dá wọn lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà wà pẹ̀lú wọn.—Sáàmù 46:7, 11.
Kó lè túbọ̀ dá àwọn èèyàn náà lójú pé Jèhófà lágbára láti dáàbò bò wọ́n, onísáàmù náà gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n ronú lórí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe. (Sáàmù 46:8) Ó tiẹ̀ dìídì sọ nípa agbára tí Ọlọ́run ní láti fòpin sí ogun. (Sáàmù 46:9) Lọ́nà kan, Jèhófà fòpin sí ogun láyé ìgbà yẹn bó ṣe dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. Àmọ́, Bíbélì sọ pé láìpẹ́ Ọlọ́run máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà tó bá fòpin sí ogun kárí ayé.—Àìsáyà 2:4.
Ṣé Jèhófà ṣì máa ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé ojú Jèhófà ni kí wọ́n máa wò fún ìrànlọ́wọ́. (Hébérù 13:6) Kò sí àní-àní pé àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 46 jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Ọlọ́run lágbára láti dáàbò bò wá. Ó sì jẹ́ ká rí i pé òun ni “ibi ààbò wa àti okun wa.”—Sáàmù 46:1.
Wo fídíò kékeré yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Sáàmù.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”