Ìgbà Wo Ni Wọ́n Kọ Ìtàn Jésù?
Ohun tí Bíbélì sọ
Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa àkọsílẹ̀ ìgbésí ayé Jésù tó kọ, ó sọ pé: “Ẹni tí ó . . . rí i ti jẹ́rìí, òótọ́ sì ni ẹ̀rí rẹ̀, ọkùnrin yẹn sì mọ̀ pé òótọ́ ni àwọn nǹkan tí òun ń sọ, kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè gbà gbọ́.”—Jòhánù 19:35.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣojú ọ̀pọ̀ èèyàn. A gbà pé òótọ́ ló wà nínú àwọn ìwé náà torí púpọ̀ lára àwọn ẹlẹ́rìí yìí ló ṣì wà láyé nígbà tí Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù kọ wọ́n. Àwọn kan sọ pé, ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn tí Kristi kú ni Mátíù kọ ìhìn rere rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 41 Sànmánì Kristẹni. Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé gbà pé ó ṣe díẹ̀ lẹ́yìn àkókò yẹn kí wọ́n tó kọ ìwé Mátíù, àmọ́ gbogbo wọn ló gbà pé ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni wọ́n kọ gbogbo ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.
Àwọn tó rí Jésù nígbà tó wà láyé, tí ikú rẹ̀ ṣojú wọn, tí wọ́n sì rí i pé ó jíǹde lè jẹ́rìí sí i pé òtítọ́ ló wà nínú àwọn ìwé Ìhìn rere. Bí ohunkóhun bá sì wà tí kì í ṣe òótọ́ nínú àwọn àkọsílẹ̀ náà, kò ní ṣòro fún wọn láti tú àṣírí rẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n F. F. Bruce kíyèsí pé: “Ọ̀kan lára ohun tó mú kí ìwàásù àwọn àpọ́sítélì wọ àwọn èèyàn lọ́kàn ni bí wọ́n ṣe máa ń fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ nípa ohun tí àwọn olùgbọ́ wọn ti mọ̀ tẹ́lẹ̀; yàtọ̀ sí pé wọ́n sọ pé, ‘A jẹ́ ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí,’ wọ́n tún sọ pé, ‘Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin fúnra yín ti mọ̀’ (Ìṣe 2:22).”