Ǹjẹ́ Bíbélì Fàyè Gba Ìkọ̀sílẹ̀?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì kò lòdì sí ìkọ̀sílẹ̀. Àmọ́ Jésù sọ ìdí kan ṣoṣo téèyàn lè fi fòpin sí ìgbéyàwó, ó ní: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè [ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni], tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.”—Mátíù 19:9.
Àwọn kan máa ń fẹ̀tàn kọ ara wọn sílẹ̀, Ọlọ́run sì kórìíra èyí. Ọlọ́run máa fìyà jẹ́ àwọn tó fi ìyàwó tàbí ọkọ wọn sílẹ̀ lọ́nà ẹ̀tàn, pàápàá àwọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí kí wọ́n lè fẹ́ ẹlòmíì.—Málákì 2:13-16; Máàkù 10:9.