Ǹjẹ́ Àwọn Ọ̀mọ̀wé Gbà Pé Jésù Wà?
Àwọn ọ̀mọ̀wé ní ìdí pàtàkì tó mú kí wọ́n gbà pé Jésù wà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ti Ọdún 2002 sọ nípa ohun tí àwọn òpìtàn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti èkejì sọ nípa Jésù àtàwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, ó ní: “Àwọn ìròyìn fi hàn pé nígbà àtijọ́ àwọn alátakò ẹ̀sìn Kristẹni pàápàá kò ṣiyè méjì pé Jésù wà, èyí táwọn kan wá ń jiyàn nípa rẹ̀ láìnídìí ní òpin ọgọ́rùn-ún ọdún kejìdínlógún, ní àárín ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún àti ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún.”
Lọ́dún 2006, ìwé Jesus and Archaeology sọ pé: “Kò sí ọ̀mọ̀wé tó ń ṣiyè méjì pé Júù tó ń jẹ́ Jésù ọmọ Jósẹ́fù ti gbé ayé rí; ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló gbà láìjanpata pé nísinsìnyí a ti mọ ohun tó pọ̀ nípa ìwà rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.”
Bíbélì fi hàn pé Jésù wà lóòtọ́. Ó sọ orúkọ àwọn babańlá rẹ̀ àti ìdílé tó ti wá. (Mátíù 1:1; 13:55) Ó tún sọ orúkọ àwọn alákòóso tí wọn ń ṣàkóso nígbà tí Jésù wà láyé. (Lúùkù 3:1, 2) Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ yẹn jẹ́ kí àwọn aṣèwádìí rí i pé ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ jóòótọ́.