Ta ni “Ááfà àti Ómégà,” Kí Ló sì Túmọ̀ Sí?
Ohun tí Bíbélì sọ
Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè ni “Ááfà àti Ómégà.” Ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọ̀rọ̀ yìí fara hàn nínú Bíbélì.—Ìṣípayá 1:8; 21:6; 22:13. a
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi pe ara rẹ̀ ní “Ááfà àti Ómégà”?
Nínú àwọn ááfábẹ́ẹ̀tì èdè Gíríìkì, ááfà ni àkọ́kọ́, ómégà ló sì gbẹ̀yìn. Èdè Gíríìkì yìí náà ni wọ́n fi kọ apá Bíbélì táwọn èèyàn máa ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun, èyí tó ní nínú ìwé Ìṣípayá. Láwọn ibi tí wọ́n ti lo àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí, ṣe ni wọ́n ń tọ́ka sí Jèhófà, pé òun nìkan ni ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin. (Ìṣípayá 21:6) Látìbẹ̀rẹ̀ ló ti jẹ́ Ọlọ́run Olódùmarè, títí láé láá sì máa jẹ́ Ọlọ́run Olódùmarè. Òun nìkan ló wà “láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 90:2.
Ta ni “ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn”?
Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ ni Bíbélì pè bẹ́ẹ̀, àmọ́ ìtumọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ní. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì tó fi hàn bẹ́ẹ̀.
Nínú Aísáyà 44:6, Jèhófà sọ pé: “Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn, yàtọ̀ sí mi, kò sí Ọlọ́run kankan.” Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé òun ni Ọlọ́run ayérayé, yàtọ̀ sí òun, kò sí ẹlòmíì. (Diutarónómì 4:35, 39) Torí náà, “ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn” níbí kò yàtọ̀ sí “Ááfà àti Ómégà.”
Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀rọ̀ náà “ẹni Àkọ́kọ́ [pro’tos, yàtọ̀ sí ááfà] àti ẹni Ìkẹyìn [e’skha·tos, kì í ṣe ómégà]” fara hàn nínú Ìṣípayá 1:17, 18 àti 2:8. Àwọn ọ̀rọ̀ tó yíká àwọn ẹsẹ yìí jẹ́ ká mọ ẹni tí wọ́n ń tọ́ka sí, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni yẹn kú, ó sì tún jíǹde. Torí náà, ó ṣe kedere pé kì í ṣe Ọlọ́run làwọn ẹsẹ yẹn ń tọ́ka sí torí pé Ọlọ́run ò lè kú. (Hábákúkù 1:12) Àmọ́ Jésù kú, a sì jí i dìde. (Ìṣe 3:13-15) Òun ni ẹni àkọ́kọ́ tó máa jí dìde sí àìleèkú ní ọ̀run, ibẹ̀ láá sì máa wà “títí láé àti láéláé.” (Ìṣípayá 1:18; Kólósè 1:18) Jésù láá máa jí àwọn òkú dìde. (Jòhánù 6:40, 44) Torí náà, òun ni ẹni Ìkẹyìn tí Jèhófà fúnra rẹ̀ jí dìde. (Ìṣe 10:40) Fún ìdí yìí, ó tọ̀nà tá a bá pe Jésù ní “ẹni Àkọ́kọ́ àti ẹni Ìkẹyìn.”
Ṣé Ìṣípayá 22:13 fi hàn pé Jésù ni “Ááfà àti Ómégà”?
Rárá. A ò mọ ẹnì tó ń sọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìṣípayá 22:13, àwọn tó sì sọ̀rọ̀ ní orí yìí pọ̀ díẹ̀. Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n William Barclay ń sọ̀rọ̀ lórí apá yìí nínú ìwé Ìṣípayá, ó sọ pé: “Wọn ò to àwọn ọ̀rọ̀ tó wà níbí lẹ́sẹẹsẹ; . . . èyí mú kó ṣòro láti mọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ gan-an.” (The Revelation of John, Volume 2, Revised Edition, ojú ìwé 223) Torí náà, ẹni tí “Ááfà àti Ómégà” ń tọ́ka sí láwọn apá ibòmíì nínú ìwé Ìṣípayá náà ni Ìṣípayá 22:13 ń tọ́ka sí, ẹni náà ni Jèhófà Ọlọ́run.
a Nínú Bíbélì King James Version ọ̀rọ̀ yìí fara hàn ní ẹ̀kẹrin nínú Ìṣípayá 1:11. Àmọ́ púpọ̀ nínú àwọn tó ń túmọ̀ Bíbélì lóde òní ò fi í sínú ìtúmọ̀ Bíbélì wọn tórí pé kò sí nínú àwọn ìwé Bíbélì tó lọ́jọ́ lórí jù lọ tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Gíríìkì, ńṣe làwọn èèyàn fi apá yẹn kún Bíbélì.