Ṣé Ọlọ́run Á Gbọ́ Àdúrà Mi?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bẹ́ẹ̀ ni, yóò gbọ́ àdúrà rẹ. Ohun tí Bíbélì sọ àti ìrírí táwọn kan ní jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà. Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù [Ọlọ́run] ni òun yóò mú ṣẹ, Igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́, yóò sì gbà wọ́n là.” (Sáàmù 145:19) Bóyá Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà tó o bá gbà tàbí kò ní gbọ́ kù sí ọwọ́ rẹ.
Ohun tó ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run
Ká gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe Jésù, Màríà, àwọn ẹni mímọ́, àwọn áńgẹ́lì tàbí ère. Jèhófà Ọlọ́run nìkan ni “Olùgbọ́ àdúrà.”—Sáàmù 65:2.
Ká gbàdúrà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run tàbí ohun tó fẹ́, èyí tó wà nínú Bíbélì.—1 Jòhánù 5:14.
Ká gbàdúrà ní orúkọ Jésù, èyí tó fi hàn pé a bọlá fún un. Jésù sọ pé: “Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.—Jòhánù 14:6.
Ká gbàdúrà láì ṣiyèméjì, ká sì máa béèrè pé kó fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i tí a kò bá ní.—Mátíù 21:22; Lúùkù 17:5.
Ká ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti òótọ́ inú. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà ga, síbẹ̀síbẹ̀, ó ń rí onírẹ̀lẹ̀.”—Sáàmù 138:6.
Má jẹ́ kó sú ẹ. Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín.”—Lúùkù 11:9.
Ohun tí kò ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run
Ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè tó o ti wá. “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
Ipò tó o wà nígbà tí ò ń gbàdúrà. O lè gbàdúrà sí Ọlọ́run lórí ìjókòó, o lè tẹrí ba, kúnlẹ̀ tàbí kó o dìde dúró.— 1 Kíróníkà 17:16; Nehemáyà 8:6; Dáníẹ́lì 6:10; Máàkù 11:25.
Bóyá o gbàdúrà sókè tàbí o gbà á sínú. Kódà Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà àgbàsínú bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó wà nítòsí rẹ lè má mọ̀ pé ò ń gbàdúrà.—Nehemáyà 2:1-6.
Bóyá ohun tó ń dà ẹ́ láàmú tóbi tàbí ó kéré. Ọlọ́run sọ fún ẹ pé kó o ‘kó gbogbo àníyàn rẹ lé òun, nítorí òun bìkítà fún ọ.’—1 Pétérù 5:7.