Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ń Ṣàìsàn Ọlọ́jọ́ Pípẹ́?

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ń Ṣàìsàn Ọlọ́jọ́ Pípẹ́?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni. Ọlọ́run máa ń bìkítà nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó bá ṣàìsàn. Nígbà tí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan ń ṣàìsàn, Bíbélì sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi.” (Sáàmù 41:3) Tó o bá ń ṣàìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́, àwọn ohun mẹ́ta yìí máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fara dà á:

  1.   Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ọ lágbára tí wàá fi lè fara dà á. O lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ,” èyí tí kò ní jẹ́ kó o máa ṣe àníyàn nípa àìsàn náà, tí wàá sì lè fara dà á láìka bó ṣe le tó.​—Fílípì 4:6, 7.

  2.   Ní èrò rere. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn. Ṣùgbọ́n ẹ̀mí tí ìdààmú bá ń mú kí àwọn egungun gbẹ.” (Òwe 17:22) Mọ béèyàn ṣe ń ṣàwàdà, torí ó máa ń lé ìbànújẹ́ lọ, yóò sì mú kí ìlera rẹ sunwọ̀n sí i.

  3.   Jẹ́ kí àwọn ìlérí Ọlọ́run máa wà lọ́kàn rẹ. Tí àwọn ìlérí Ọlọ́run bá jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ, èyí á máa fún ẹ láyọ̀ láìka bí àìsàn náà ṣe le sí. (Róòmù 12:12) Bíbélì sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí kò ní “sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Ọlọ́run máa wo àwọn àìsàn tó le gan-an sàn, èyí tó ti kọjá agbára ìṣègùn òde òní. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé àwọn tó ti darúgbó yóò pa dà di ọ̀dọ́, ó ní: “Kí ara rẹ̀ jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe; Kí ó padà sí àwọn ọjọ́ okun inú ti ìgbà èwe rẹ̀.”​—Jóòbù 33:5.

 Àkíyèsí: Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà lóòtọ́ pé Ọlọ́run máa ń ràn wá lọ́wọ́, a sì máa ń tọ́jú ara wa ní ilé ìwòsàn tá a bá ń ṣàìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́. (Máàkù 2:17) Àmọ́ ṣá o, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní sọ irú ìtọ́jú kan pàtó tó yẹ kó o gbà lọ́dọ̀ àwọn dókítà fún ẹ; olúkálukú ni yóò pinnu irú ìtọ́jú tó fẹ́ fúnra rẹ̀.