Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Àpótí Májẹ̀mú?

Kí Ni Àpótí Májẹ̀mú?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Àpótí májẹ̀mú ni àpótí mímọ́ kan tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe láyé àtijọ́. Wọ́n tẹ̀ lé àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún wọn nípa bí wọ́n á ṣe ṣe é kó lè rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́. Inú àpótí yìí ni “ẹ̀rí” wà, ìyẹn Òfin Mẹ́wàá tí wọ́n kọ sórí wàláà òkúta méjì.​—Ẹ́kísódù 25:8-​10, 16; 31:18.

  •   Bí wọ́n ṣe ṣe àpótí náà. Ìgbọ̀nwọ́ méjì àtààbọ̀ ni gígùn Àpótí náà, ìgbọ̀nwọ́ kan àtààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àtààbọ̀ sì ni gíga rẹ̀. Igi bọn-ọ̀n-ní ni wọ́n fi ṣe àpótí náà, wọ́n fi wúrà bò ó tinú-tòde, wọ́n sì fi iṣẹ́ ọnà ṣe ìgbátí sí etí rẹ̀ yí ká. Kìkì wúrà ni wọ́n fi ṣe ìbòrí rẹ̀, wọ́n sì fi wúrà ṣe kérúbù méjì sí ìkángun rẹ̀ méjèèjì. Àwọn kérúbù náà dojú kọra wọn, wọ́n sì kọjú sí ìbòrí náà. Wọ́n na ìyẹ́ wọn sókè, ó sì bo ìbòrí náà. Àpótí náà ní òrùka mẹ́rin tí wọ́n fi wúrà ṣe sí òkè ẹsẹ̀ rẹ̀. Wọ́n wá fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá, wọ́n sì fi wúrà bò ó. Àwọn ọ̀pá yìí ni wọ́n máa ń kì bọ àwọn òrùka náà láti máa fi gbé Àpótí náà.​—Ẹ́kísódù 25:10-​21; 37:6-9.

  •   Ibi tó máa ń wà. Níbẹ̀rẹ̀, inú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ní àgọ́ ìjọsìn ni Àpótí náà máa ń wà. Àgọ́ ìjọsìn náà ṣeé gbé kiri, ìgbà kan náà tí wọ́n ṣe àgọ́ yìí ni wọ́n sì ṣe Àpótí náà. Wọ́n ta aṣọ ìkélé bo Ibi Mímọ́ Jù Lọ káwọn àlùfáà àtàwọn èèyàn má bàa rí i. (Ẹ́kísódù 40:3, 21) Àlùfáà àgbà nìkan ló lè wọ ibẹ̀, kó sì rí Àpótí náà. Ọjọ́ Ètùtù tí wọ́n máa ń ṣe lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ló máa ń wọ ibẹ̀. (Léfítíkù 16:2; Hébérù 9:7) Nígbà tó yá, wọ́n gbé àpótí náà lọ sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ní tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́.​—1 Kings 6:14, 19.

  •   Ohun tó wà fún. Àwọn ohun mímọ́ táá máa rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá wọn dá ní Òkè Sínáì ni wọ́n máa ń kó sínú Àpótí náà. Ó tún ní ipa pàtàkì tó máa ń kó nínú ayẹyẹ Ọjọ́ Ètùtù.​—Léfítíkù 16:3, 13-17.

  •   Àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀. Àwọn wàláà òkúta tí wọ́n kọ Òfin Mẹ́wàá sí ni wọ́n kọ́kọ́ gbé sínú Àpótí náà. (Ẹ́kísódù 40:20) Nígbà tó yá, wọ́n gbé ìṣà kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, èyí tí wọ́n rọ mánà sí sínú rẹ̀, wọ́n tún fi “ọ̀pá Áárónì tí ó rudi” sínú rẹ̀. (Hébérù 9:4; Ẹ́kísódù 16:33, 34; Númérì 17:10) Ó ní láti jẹ́ pé wọ́n gbé ìṣà àti ọ̀pá náà kúrò nígbà kan, torí kò sí nínú Àpótí náà nígbà tí wọ́n gbé e wọnú tẹ́ńpìlì.​—1 Àwọn Ọba 8:9.

  •   Bí wọ́n ṣe ń gbé e. Àwọn ọmọ Léfì ló máa ń fi èjìká ru Àpótí náà, àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe ni wọ́n sì máa ń fi gbé e. (Númérì 7:9; 1 Kíróníkà 15:15) Àwọn ọmọ Léfì kì í fọwọ́ kan Àpótí náà torí wọn kì í fìgbà kankan yọ àwọn ọ̀pá náà kúrò lára rẹ̀. (Ẹ́kísódù 25:12-​16) “Aṣọ ìkélé àtabojú” tí wọ́n fi pín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ ni wọ́n máa ń fi bo Àpótí náà tí wọ́n bá fẹ́ gbé e.​—Númérì 4:5, 6. a

  •   Ohun tó ṣàpẹẹrẹ. Àmì pé Ọlọ́run wà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Àpótí náà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ìkùukùu tó máa ń wà lórí Àpótí náà nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ àti níbi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá pàgọ́ sí jẹ́ àmì pé Jèhófà wà láàárín wọn, ó sì ń bù kún wọn. (Léfítíkù 16:2; Númérì 10:33-​36) Bákan náà, Bíbélì sọ pé Jèhófà “jókòó lórí àwọn kérúbù,” ìyẹn àwọn kérúbù méjèèjì tó wà lórí ìbòrí Àpótí náà. (1 Sámúẹ́lì 4:4; Sáàmù 80:1) Torí náà, “àwòrán kẹ̀kẹ́ ẹṣin” Jèhófà ni àwọn kérúbù yìí. (1 Kíróníkà 28:18) Torí Ọba Dáfídì mọ ohun tí Àpótí náà ṣàpẹẹrẹ ló fi kọ ohun tó wà nínú Bíbélì pé Jèhófà “ń gbé Síónì” lẹ́yìn tí wọ́n gbé Àpótí náà débẹ̀.​—Sáàmù 9:11.

  •   Àwọn orúkọ tó ń jẹ́. Oríṣiríṣi orúkọ ni Bíbélì pe àpótí mímọ́ yìí. Ó pè é ní “àpótí gbólóhùn ẹ̀rí,” “àpótí májẹ̀mú,” “àpótí Jèhófà,” àti “Àpótí okun [Jèhófà].”​—Númérì 7:89; Jóṣúà 3:6, 13; 2 Kíróníkà 6:41.

     Bíbélì pe ìbòrí Àpótí náà ní “ìbòrí ìpẹ̀tù,” tàbí “ibùjókòó àánú.” (1 Kíróníkà 28:11; Bíbélì Mímọ́) Ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí iṣẹ́ pàtàkì tí ìbòrí náà máa ń ṣe ní Ọjọ́ Ètùtù, nígbà tí àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì bá wọ́n ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran tí wọ́n fi rúbọ sí apá ibi tí ìbòrí náà wà àti iwájú ìbòrí náà. Àwọn ohun tí àlùfáà àgbà ń ṣe yìí ló fi n ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ “ara rẹ̀ àti . . . ilé rẹ̀ àti . . . gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì pátá.”​—Léfítíkù 16:14-​17.

Ṣé àpótí májẹ̀mú yẹn ṣì wà dòní?

 Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé ó ṣì wà. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Àpótí náà ò níṣẹ́ tó fẹ́ ṣe mọ́ torí pé Ọlọ́run ti fi “májẹ̀mú tuntun” tó dá lórí ẹbọ ìràpadà Jésù rọ́pò májẹ̀mú tó ní ín ṣe pẹ̀lú Àpótí náà.. (Jeremáyà 31:31-​33; Hébérù 8:13; 12:24) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí kò ní sí àpótí májẹ̀mú mọ́, àwọn èèyàn Ọlọ́run ò sì ní sàárò rẹ̀.​—Jeremáyà 3:16.

 Àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran kan lẹ́yìn tí májẹ̀mú tuntun fìdí múlẹ̀. Nínú ìran náà, ó rí àpótí májẹ̀mú ní ọ̀run. (Ìṣípayá 11:15, 19) Àpótí ìṣàpẹẹrẹ yìí jẹ́ àmì pé Ọlọ́run wà nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀, ìbùkún rẹ̀ sì wà lórí májẹ̀mú tuntun náà.

Ṣé Àpótí náà ní agbára àràmàǹdà kan láti dáàbò boni?

 Rárá o. Pé àpótí májẹ̀mú náà wà níbì kan ò túmọ̀ sí pé nǹkan á máa lọ dáadáa níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Àpótí májẹ̀mú wà nínú àgọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ń bá àwọn ará ìlú Áì jà, síbẹ̀ àwọn ará ìlú Áì ṣẹ́gun wọn torí ọmọ Ísírẹ́lì kan ṣe ohun tí ò dáa. (Jóṣúà 7:1-6) Nígbà tó yá, àwọn Filísínì náà ṣẹ́gun wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú lọ sójú ogun. Ìwà burúkú tí Hófínì àti Fíníhásì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà ní Ísírẹ́lì hù ló kó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́tẹ̀ yìí. (1 Sámúẹ́lì 2:12; 4:1-​11) Lójú ogun yẹn, àwọn Filísínì gbé Àpótí náà lọ àmọ́ Ọlọ́run fi àrùn ṣe wọ́n títí wọ́n fi dá àpótí náà pa dà sí Ísírẹ́lì.​—1 Sámúẹ́lì 5:11–6:5.

 Ìtàn àpótí májẹ̀mú náà

 Ọdún (Ṣ.Ṣ.K.)

 Ohun tó ṣẹlẹ̀

 1513

 Bẹ́sálẹ́lì àtàwọn tó bá a ṣiṣẹ́ fi ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣètìlẹyìn ṣe àpótí náà.​—Ẹ́kísódù 25:1, 2; 37:1.

 1512

 Mósè ya àpótí náà àti àgọ́ ìjọsìn sí mímọ́, ó sì ya àwọn àlùfáà sí mímọ́.​—Ẹ́kísódù 40:1-3, 9, 20, 21.

 1512 sí ẹ̀yìn ọdún 1070

 Wọ́n ń gbé e káàkiri.​—Jóṣúà 18:1; Àwọn Onídàájọ́ 20:26, 27; 1 Sámúẹ́lì 1:24; 3:3; 6:11-​14; 7:1, 2.

 Lẹ́yìn ọdún 1070

 Ọba Dáfídì gbé e wá sí Jerúsálẹ́mù.​—2 Sámúẹ́lì 6:12.

 1026

 Wọ́n gbé e wọ tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ ní Jerúsálẹ́mù.​—1 Àwọn Ọba 8:1, 6.

 642

 Ọba Jòsáyà dá a pa dà sí tẹ́ńpìlì.​—2 Kíróníkà 35:3. b

 Ṣáájú 607

 Ó jọ pé wọ́n gbé e kúrò ní tẹ́ńpìlì. Wọn ò kà á mọ́ àwọn ohun tí wọ́n kó lọ sí Bábílónì nígbà táwọn ará Bábílónì pa tẹ́ńpìlì náà run lọ́dún 607 Ṣ.S.K, wọn ò sì kà á mọ́ àwọn ohun tí wọ́n kó pa dà sí Jerúsálẹ́mù nígbà tó yá.​—2 Àwọn Ọba 25:13-​17; Ẹ́sírà 1:7-​11.

 63

 Ọ̀gágun ilẹ̀ Róòmù tó ń jẹ́ Pompey ṣẹ́gun ìlú Jerúsálẹ́mù, ó sì kéde pé òun ò rí àpótí náà nígbà tó lọ wo Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì náà. c

a Ọlọ́run fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gidigidi torí wọ́n rú òfin tí Ọlọ́run ṣe nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa gbé Àpótí náà, kí wọ́n sì máa bò ó.​—1 Sámúẹ́lì 6:19; 2 Sámúẹ́lì 6:2-7.

b Bíbélì ò sọ ìgbà tí wọ́n gbé e kúrò tẹ́lẹ̀, ìdí tí wọ́n fi gbé e kúrò àti ẹni tó gbé e kúrò.

c Wo ìwé náà, The Histories, by Tacitus, Book V, ìpínrọ̀ 9.