Ta Ni Aṣòdì sí Kristi?
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Aṣòdì sí Kristi kì í ṣe ẹni kan tàbí ohun kan tó dá wà, torí Bíbélì sọ pé ‘ọ̀pọ̀ aṣòdì sí Kristi ni ó wà.’ (1 Jòhánù 2:18) Ọ̀rọ̀ náà “aṣòdì sí Kristi” wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “ta ko (tàbí dípò) Kristi,” àwọn tó bá sì ń hu irú àwọn ìwà tó wà nísàlẹ̀ yìí ni aṣòdì sí Kristi:
Wọn kò gba pé Jésù ni Kristi (Mèsáyà) àbí kí wọn má gbà pé ọmọ Ọlọ́run ni.—1 Jòhánù 2:22.
Wọ́n ta ko Kristi, Ẹni Àmì Òróró Ọlọ́run.—Sáàmù 2:1, 2; Lúùkù 11:23.
Wọn pe ara wọn ní Kristi.—Mátíù 24:24.
Wọ́n máa ń ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi níwọ̀n bí Jésù ti gbà pé tí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn òun wọ́n ti ṣe é sí òun.—Ìṣe 9:5.
Wọ́n ń pe ara wọn ní Kristẹni síbẹ̀ wọ́n ń hùwà àìlófin tàbí ìwà ẹ̀tàn.—Mátíù 7:22, 23; 2 Kọ́ríńtì 11:13.
Yàtọ̀ sí pé a lè pe ẹnì kan ní aṣòdì sí Kristi, Bíbélì tún pe gbogbo àwọn tó ń hùwà yìí lápapọ̀ ní “aṣòdì sí Kristi.” (2 Jòhánù 7) Ìgbà ayé àwọn àpọ́sítélì ni aṣòdì sí Kristi ti kọ́kọ́ fara hàn, wọ́n ṣì wà títí di báyìí. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn aṣòdì sí Kristi yóò wà.—1 Jòhánù 4:3.
Bí a ṣe lè dá àwọn aṣòdì sí Kristi mọ̀
Wọ́n ń tan èrò tí kò tọ́ nípa Jésù kálẹ̀. (Mátíù 24:9, 11) Bí àpẹẹrẹ àwọn tó ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan tàbí pé Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè ń ta kò ẹ̀kọ́ tí Jésù fi ń kọ́ni pé: “Baba tóbi jù mí lọ.”—Jòhánù 14:28.
Àwọn aṣòdì sí Kristi kò gbà pẹ̀lú ohun tí Jésù sọ nípa bí ìjọba Ọlọ́run ṣe máa ṣàkóso. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan sọ pé Kristi ló ń darí ìjọba èèyàn. Síbẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí kò bá ohun tí Jésù sọ mu pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.”—Jòhánù 18:36.
Wọ́n ń sọ pé Jésù ni Olúwa, síbẹ̀ wọn kò pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, tó fi mọ́ èyí tó pa pé kí wọ́n wàásù ìhìn rere Ìjọba náà.—Mátíù 28:19, 20; Lúùkù 6:46; Ìṣe 10:42.