Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà Fẹ̀rí Hàn Pé Jésù Ni Mèsáyà Náà?

Ṣé Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà Fẹ̀rí Hàn Pé Jésù Ni Mèsáyà Náà?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ nípa “Mèsáyà Aṣáájú,” ẹni tó máa jẹ́ “Olùgbàlà ayé.” (Dáníẹ́lì 9:25; 1 Jòhánù 4:14) Kódà lẹ́yìn tí Jésù kú, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ṣì ń ṣẹ sí i lára.​—Sáàmù 110:1; Ìṣe 2:34-​36.

 Kí ni ìtumọ̀ “Mèsáyà”?

 Ọ̀rọ̀ Hébérù náà Ma·shiʹach (ìyẹn Mèsáyà) àti ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà Khri·stos (ìyẹn Kristi) túmọ̀ sí “Ẹni Àmì Òróró.” Torí náà, ohun tí orúkọ náà “Jésù Kristi” túmọ̀ sí ni “Jésù, Ẹni Àmì Òróró,” tàbí “Jésù, Mèsáyà Náà.”

 Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, tí wọ́n bá fẹ́ yan ẹnì kan sípò àṣẹ, ṣe ni wọ́n sábà máa ń da òróró sí i lórí. (Léfítíkù 8:12; 1 Sámúẹ́lì 16:13) Ọlọ́run ló yan Jésù ṣe Mèsáyá, ipò àṣẹ ńlá ló sì jẹ́. (Ìṣe 2:36) Àmọ́ dípò kí Ọlọ́run fi òróró yan Jésù, ẹ̀mí mímọ́ ló fi yàn án.​—Mátíù 3:16.

 Ṣé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà lè ṣẹ sára ẹni méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ?

 Rárá. Tí ẹnì kan bá tẹ̀ka, kò lè jọ ti ẹlòmíì láé. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa Mèsáyà tàbí Kristi, ẹnì kan ṣoṣo ló ń tọ́ka sí. Àmọ́ Bíbélì kìlọ̀ pé “àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde, wọn yóò sì fúnni ní àwọn àmì ńláǹlà àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu láti ṣi àwọn àyànfẹ́ pàápàá lọ́nà, bí ó bá ṣeé ṣe.”​—Mátíù 24:24.

 Ǹjẹ́ Mèsáyà lè fara hàn lọ́jọ́ iwájú?

 Rárá. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ọba Dáfídì ti Ísírẹ́lì. (Sáàmù 89:3, 4) Àmọ́ àwọn àkọsílẹ̀ ìlà ìdílé àwọn Júù tá a lè tọpasẹ̀ rẹ̀ dórí Dáfídì ti sọ nù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà táwọn ará Róòmù ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 70 S.K ni wọ́n pa á run. a Àtìgbà yẹn ni kò ti ṣeé ṣe kí ẹnikẹ́ni tó bá ń sọ pé ìdílé Ọba Dáfídì lòun ti wá rí ẹ̀rí fi tì í lẹ́yìn. Àmọ́ àwọn àkọsílẹ̀ yẹn ṣì wà nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá ò lè sọ pé irọ́ ló ń pa nígbà tó pe ara rẹ̀ ní àtọmọdọ́mọ Dáfídì.​—Mátíù 22:41-​46.

 Àsọtẹ́lẹ̀ mélòó nípa Mèsáyà ló wà nínú Bíbélì?

 Kò ṣeé ṣe láti sọ pé iye báyìí ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nípa Mèsáyà. Bí àpẹẹrẹ, nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ Mèsáyà ni wọ́n ń sọ níbẹ̀ pàápàá, bí àwọn èèyàn ṣe máa ka iye àsọtẹ́lẹ̀ tó wà níbẹ̀ lè yàtọ̀ síra. Àkọsílẹ̀ Aísáyà 53:2-7 mẹ́nu ba ohun mélòó kan tó máa ṣẹlẹ̀ sí Mèsáyà. Àwọn kan lè ka gbogbo ohun tó wà nínú àwọn ẹsẹ yẹn sí àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣoṣo, àwọn míì sì lè ka ìṣẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan sí àsọtẹ́lẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Mèsáyà tó ṣẹ sí Jésù lára

 Àsọtẹ́lẹ̀

 Ibi tó wà

 Ìmúṣẹ

 Ọmọ Ábúráhámù ni

 Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18

 Mátíù 1:1

 Àtọmọdọ́mọ Ísákì ọmọ Ábúráhámù ni

 Jẹ́nẹ́sísì 17:19

 Mátíù 1:2

 Wọ́n máa bí i ní ẹ̀yà Júdà ti Ísírẹ́lì

 Jẹ́nẹ́sísì 49:10

 Mátíù 1:1, 3

 Ó máa wá láti ìlà ìdílé Ọba Dáfídì

 Aísáyà 9:7

 Mátíù 1:1

 Wúńdíá ló máa bí i

 Aísáyà 7:14

 Mátíù 1:18, 22, 23

 Wọ́n máa bí i ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù

 Míkà 5:2

 Mátíù 2:1, 5, 6

 Wọ́n máa pè é ní Ìmánúẹ́lì b

 Aísáyà 7:14

 Mátíù 1:21-​23

 Ilé tó rẹlẹ̀ ló ti máa wá

 Aísáyà 53:2

 Lúùkù 2:7

 Wọ́n pa àwọn ọmọdé lẹ́yìn tí wọ́n bí i

 Jeremáyà 31:15

 Mátíù 2:16-​18

 Wọ́n pè é jáde láti Íjíbítì

 Hóséà 11:1

 Mátíù 2:13-​15

 Wọ́n pè é ní ará Násárétì c

 Aísáyà 11:1

 Mátíù 2:23

 Ìránṣẹ́ kan máa ṣáájú rẹ̀ wá

 Málákì 3:1

 Mátíù 11:7-​10

 A yàn án láti di Mèsáyà ní 29 S.K. d

 Dáníẹ́lì 9:25

 Mátíù 3:13-​17

 Ọlọ́run pè é ní Ọmọ Rẹ̀

 Sáàmù 2:7

 Ìṣe 13:33, 34

 Ó nítara fún ilé Ọlọ́run

 Sáàmù 69:9

 Jòhánù 2:13-​17

 Ó kéde ìhìn rere

 Aísáyà 61:1

 Lúùkù 4:16-​21

 Iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Gálílì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ńlá

 Aísáyà 9:1, 2

 Mátíù 4:13-​16

 Oníṣẹ́ ìyanu ni bíi ti Mósè

 Diutarónómì 18:15

 Ìṣe 2:22

 Ó sọ èrò Ọlọ́run bíi ti Mósè

 Diutarónómì 18:18, 19

 Jòhánù 12:49

 Ó wo ọ̀pọ̀ aláìsàn sàn

 Aísáyà 53:4

 Mátíù 8:16, 17

 Kò pe àfíyèsí sí ara rẹ̀

 Aísáyà 42:2

 Mátíù 12:17, 19

 Ó ṣàánú àwọn tí ìyà ń jẹ

 Aísáyà 42:3

 Mátíù 12:9-​20; Máàkù 6:34

 Ó fi ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run hàn

 Aísáyà 42:1, 4

 Mátíù 12:17-​20

 Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn ni

 Aísáyà 9:6, 7

 Jòhánù 6:68

 Ó kéde orúkọ Jèhófà

 Sáàmù 22:22

 Jòhánù 17:6

 Àpèjúwe ló fi ń sọ̀rọ̀

 Sáàmù 78:2

 Mátíù 13:34, 35

 Aṣáájú ni

 Dáníẹ́lì 9:25

 Mátíù 23:10

 Ọ̀pọ̀ ni kò gbà á gbọ́

 Aísáyà 53:1

 Jòhánù 12:37, 38

 Ó jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀

 Aísáyà 8:14, 15

 Mátíù 21:42-​44

 Àwọn èèyàn ò gba tiẹ̀

 Sáàmù 118:22, 23

 Ìṣe 4:10, 11

 Wọ́n kórìíra ẹ̀ láìnídìí

 Sáàmù 69:4

 Jòhánù 15:24, 25

 Ó máa gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù

 Sekaráyà 9:9

 Mátíù 21:4-9

 Àwọn ọmọdé máa yìn ín

 Sáàmù 8:2

 Mátíù 21:15, 16

 Ó máa wá ní orúkọ Jèhófà

 Sáàmù 118:26

 Jòhánù 12:12, 13

 Ọ̀rẹ́ tó fọkàn tán máa dà á

 Sáàmù 41:9

 Jòhánù 13:18

 Ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà ni wọ́n fún ẹni tó dà á e

 Sekaráyà 11:12, 13

 Mátíù 26:14-​16; 27:3-​10

 Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pa á tì

 Sekaráyà 13:7

 Mátíù 26:31, 56

 Àwọn ẹlẹ́rìí èké ta kò ó

 Sáàmù 35:11

 Mátíù 26:59-​61

 Kò sọ̀rọ̀ níwájú àwọn tó ń fẹ̀sùn kàn án

 Aísáyà 53:7

 Mátíù 27:12-​14

 Wọ́n tutọ́ sí i lára

 Aísáyà 50:6

 Mátíù 26:67; 27:27, 30

 Wọ́n gbá a ní orí

 Míkà 5:1

 Máàkù 15:19

 Wọ́n nà án

 Aísáyà 50:6

 Jòhánù 19:1

 Kò bá àwọn tó lù ú jà

 Aísáyà 50:6

 Jòhánù 18:22, 23

 Àwọn aṣáájú ìjọba lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ ọn

 Sáàmù 2:2

 Lúùkù 23:10-​12

 Wọ́n kan ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ mọ́gi

 Sáàmù 22:16

 Mátíù 27:35; Jòhánù 20:25

 Àwọn èèyàn ṣẹ́ kèké (tàbí ta tẹ́tẹ́) lórí aṣọ rẹ̀

 Sáàmù 22:18

 Jòhánù 19:23, 24

 Wọ́n kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀

 Aísáyà 53:12

 Mátíù 27:38

 Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tí ò dáa sí i

 Sáàmù 22:7, 8

 Mátíù 27:39-​43

 Ó jìyà nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀

 Aísáyà 53:5, 6

 1 Pétérù 2:23-​25

 Ó jọ pé Ọlọ́run ti pa á tì

 Sáàmù 22:1

 Máàkù 15:34

 Wọ́n fún un ní ọtí kíkan àti òróró mu

 Sáàmù 69:21

 Mátíù 27:34

 Òùngbẹ gbẹ ẹ́ nígbà tó ku díẹ̀ kó kú

 Sáàmù 22:15

 Jòhánù 19:28, 29

 Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́

 Sáàmù 31:5

 Lúùkù 23:46

 Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀

 Aísáyà 53:12

 Máàkù 15:37

 Ó pèsè ìràpadà láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò

 Aísáyà 53:12

 Mátíù 20:28

 Wọn ò ṣẹ́ ẹgungun rẹ̀

 Sáàmù 34:20

 Jòhánù 19:31-​33, 36

 Wọ́n gún un lọ́kọ̀

 Sekaráyà 12:10

 Jòhánù 19:33-​35, 37

 Wọ́n sin ín pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀

 Aísáyà 53:9

 Mátíù 27:57-​60

 A jí i dìde

 Sáàmù 16:10

 Ìṣe 2:29-​31

 Wọ́n fi ẹlòmíì rọ́pò ẹni tó dà á

 Sáàmù 109:8

 Ìṣe 1:15-​20

 Ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run

 Sáàmù 110:1

 Ìṣe 2:34-​36

a Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ McClintock and Strong’s Cyclopedia sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí ẹni tó lè jiyàn ẹ̀ pé ìgbà tí Jerúsálẹ́mù pa run ni àwọn àkọsílẹ̀ ìran àwọn Júù àti ìlà ìdílé wọn pa run, pé kì í ṣe ṣáájú ìgbà yẹn.”

b Orúkọ Hébérù náà, Ìmánúẹ́lì, tó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa,” jẹ́ ká mọ ohun tí Jésù máa ṣe gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà. Wíwá tó wá sáyé àtàwọn iṣẹ́ tó ṣe fẹ̀rí hàn pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn olùjọ́sìn Rẹ̀.​—Lúùkù 2:27-​32; 7:12-​16.

c Ó jọ pé inú ọ̀rọ̀ Hébérù náà neʹtser, tó túmọ̀ sí “èéhù” ni ọ̀rọ̀ náà “ará Násárétì” ti wá.

d Tó o bá fẹ́ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn déètì ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì tó tọ́ka sí ọdún 29 S.K. gẹ́gẹ́ bí ọdún tí Mèsáyà fara hàn, wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Bí Dáníẹ́lì Ṣe Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìgbà Tí Mèsáyà Yóò Dé.”

e Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ìwé Sekaráyà ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí wà, síbẹ̀ Mátíù tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé “nípasẹ̀ Jeremáyà wòlíì” la ṣe sọ ọ́. (Mátíù 27:9) Ó jọ pé nígbà míì, wọ́n máa ń fi ìwé Jeremáyà ṣáájú nínú apá tá a pè ní “Àwọn Wòlíì” nínú Ìwé Mímọ́. (Lúùkù 24:44) Ó jọ pé ṣe ni Mátíù pe àpapọ̀ àwọn ìwé kan, tó fi mọ́ ìwé Sekaráyà ní “Jeremáyà.”