Àwọn Wo Ni “Amòye Mẹ́ta Náà”? Ṣé “Ìràwọ̀” Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Ni Wọ́n Tẹ̀ Lé?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ní àsìkò Kérésìmesì, àwọn èèyàn sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “àwọn amòye mẹ́ta” tàbí “àwọn ọba mẹ́ta” láti ṣàpèjúwe àwọn arìnrìn-àjò tí wọ́n lọ rí Jésù lẹ́yìn tí wọ́n bí i, bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti lo ọ̀rọ̀ náà. (Mátíù 2:1) Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà ma’goi ni Mátíù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere lò láti ṣàpèjúwe àwọn tó wá kí Jésù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n ń lò fún àwọn ògbóǹkangí nínú iṣẹ́ awòràwọ̀ àtàwọn ohun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ awo. a Àwọn Bíbélì kan pè wọ́n ní “awòràwọ̀” tàbí “onídán.” b
“Àwọn amòye” mélòó ló wà níbẹ̀?
Bíbélì ò sọ fún wa, ohun tí ọ̀pọ̀ ìtàn sọ nípa iye wọn sì yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Encyclopedia Britannica sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ Éṣíà gbà pé méjìlá (12) làwọn amòye náà, àwọn tó ń gbé ní Yúróòpù àti Amẹ́ríkà sì gbà pé mẹ́ta ni wọ́n, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí ẹ̀bùn mẹ́ta tí wọ́n fún ọmọ náà, ìyẹn ‘wúrà, oje igi tùràrí àti òjíá.’” (Mátíù 2:11)
Ṣé ọba ni “àwọn amòye” náà?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú àṣà Kérésìmesì, wọ́n sábà máa ń ṣàpèjúwe àwọn àlejò yẹn bí ọba, àmọ́ kò síbì kankan tí Bíbélì ti pè wọ́n ní ọba. Ìwé Encyclopedia Britannica sọ pé, ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù làwọn èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ pe àwọn amòye náà ní ọba, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe “àbùmọ́ ìtàn náà.”
Kí ni orúkọ “àwọn amòye” náà?
Bíbélì ò sọ orúkọ àwọn awòràwọ̀ náà. Bíbélì The International Standard Bible Encyclopedia sọ pé àwọn ‘ìtàn àròsọ àtàwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu kan sọ pé Gaspar, Melchior àti Balthasar lorúkọ wọn.’
Ìgbà wo ni “àwọn amòye” náà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Jésù?
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù ni àwọn awòràwọ̀ náà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé nígbà tí Ọba Hẹ́rọ́dù tó ń wọ́nà àtipa Jésù pàṣẹ pé kí wọ́n pa àwọn ọmọkùnrin, àwọn ọmọ ọdún méjì sísàlẹ̀ ló ní kí wọ́n pa. Ohun tó gbọ́ lẹ́nu àwọn awòràwọ̀ yẹn ló fi ṣírò ẹ̀ pé ọmọ tóun fẹ́ pa náà kò tíì lè kọjá ọdún méjì.—Mátíù 2:16.
Kì í ṣe alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù ni àwọn awòràwọ̀ náà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí wọ́n sì wọ ilé náà, wọ́n rí ọmọ kékeré náà pẹ̀lú Màríà ìyá rẹ̀.” (Mátíù 2:11) Èyí fi hàn pé inú ilé ni Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ ń gbé báyìí àti pé Jésù ti kúrò lọ́mọ ọwọ́ tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran.—Lúùkù 2:16.
Ṣé Ọlọ́run ló sọ pe kí “àwọn amòye” yẹn tẹ̀ lé “ìràwọ̀” Bẹ́tílẹ́hẹ́mù?
Àwọn kan pe ìràwọ̀ yẹn ní ìràwọ̀ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, wọ́n sì gbà pé Ọlọ́run ló rán an láti darí àwọn awòràwọ̀ yẹn lọ sọ́dọ̀ Jésù. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀.
Jerúsálẹ́mù ni ohun tó dà bí ìràwọ̀ yẹn kọ́kọ́ darí àwọn awòràwọ̀ náà lọ. Bíbélì sọ pé: “Àwọn awòràwọ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù láti Ìlà Oòrùn, wọ́n sọ pé: ‘Ibo ni ọba àwọn Júù tí wọ́n bí wà? Torí a rí ìràwọ̀ rẹ̀ nígbà tí a wà ní Ìlà Oòrùn, a sì ti wá ká lè forí balẹ̀ fún un.’”—Mátíù 2:1, 2.
Ọba Hẹ́rọ́dù ló kọ́kọ́ darí àwọn awòràwọ̀ náà lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù kì í ṣe “ìràwọ̀” náà. Nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́ pé “ọba àwọn Júù” kan wà tó yàtọ̀ sí òun, ó ṣe ìwádìí nípa ibi tí wọ́n máa bí Kristi náà sí. (Mátíù 2:3-6) Nígbà tó wá mọ̀ pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni, ó sọ fún àwọn awòràwọ̀ náà pé kí wọ́n lọ síbẹ̀ láti lọ wo ọmọ náà, kí wọ́n sì pa dà wá ròyìn fún òun.
Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn awòràwọ̀ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Bíbélì sọ pé: “Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ohun tí ọba sọ, wọ́n lọ, sì wò ó! ìràwọ̀ tí wọ́n rí nígbà tí wọ́n wà ní Ìlà Oòrùn ń lọ níwájú wọn, títí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ kékeré náà wà.”—Mátíù 2:9.
Lẹ́yìn tí “ìràwọ̀” náà fara hàn, onírúurú nǹkan tí kò dáa ṣẹlẹ̀ débi pé díẹ̀ ló kù kí wọ́n pa Jésù, kódà àìmọye ọmọ ni wọ́n gbẹ̀mí ẹ̀. Nígbà tí àwọn awòràwọ̀ náà kúrò ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Ọlọ́run kìlọ̀ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ pa dà sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù.—Mátíù 2:12.
Kí ni Hẹ́rọ́dù wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí Hẹ́rọ́dù rí i pé àwọn awòràwọ̀ náà ti já ọgbọ́n òun, inú bí i gidigidi, ó ránṣẹ́, ó sì ní kí wọ́n pa gbogbo ọmọkùnrin ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti ní gbogbo agbègbè rẹ̀, láti ọmọ ọdún méjì sí ìsàlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àkókò tó fara balẹ̀ wádìí lọ́wọ́ àwọn awòràwọ̀ náà.” (Mátíù 2:16) Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run kọ́ ló rán ìràwọ̀ yẹn wá torí Ọlọ́run kò lè fa irú ohun burúkú bẹ́ẹ̀ láéláé.—Jóòbù 34:10.
a Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tó ń jẹ́ Herodotus tó gbé ní 2,500 ọdún sẹ́yìn sọ pé ẹ̀yà Mídíánì (Páṣíà) làwọn maʹgoi (àwọn amòye) tó wà láyé ìgbà yẹn, ìràwọ̀ wíwo àti títúmọ̀ àlá sì ni iṣẹ́ wọn.
b Wo New American Standard Bible, The New American Bible, The New English Bible àti the New International Version Study Bible. Bíbélì King James Version pe àwọn àlejò yìí ní “àwọn amòye” ṣùgbọ́n kò sọ pé mẹ́ta ni wọ́n.