Kí Ni “Àwọn Kọ́kọ́rọ́ Ìjọba”?
Ohun tí Bíbélì sọ
“Àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba,” tá a tún mọ̀ sí “àwọn kọ́kọ́rọ́ àtiwọ ìjọba,” dúró fún àṣẹ láti ṣínà fún àwọn èèyàn kí wọ́n lè “wọ ìjọba Ọlọ́run.” (Mátíù 16:19; The New American Bible; Ìṣe 14:22) a Jésù fún Pétérù ní “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run.” Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé Pétérù gba àṣẹ láti jẹ́ ká mọ̀ pé tí àwọn olóòótọ́ èèyàn bá gba ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, wọ́n lè láǹfààní láti wọ Ìjọba ọ̀run.
Àwọn wo ni Pétérù lo kọ́kọ́rọ́ náà fún?
Pétérù fi àṣẹ tí Ọlọ́run fún un láti ṣí ọ̀nà fún àwùjọ èèyàn mẹ́ta láti wọ Ìjọba náà:
Àwọn Júù àtàwọn tó yí pa dà di Júù. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù kú tí Pétérù rọ ọ̀pọ̀ àwọn Júù pé kí wọ́n gba Jésù ní ẹni tí Ọlọ́run yàn láti jẹ́ ọba Ìjọba náà. Pétérù fi ohun tí wọ́n máa ṣe kí wọ́n lè rígbàlà hàn wọ́n. Bó ṣe ṣínà fún wọn nìyẹn, kí wọ́n lè wọ Ìjọba náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ló sì “gba ọ̀rọ̀ rẹ̀.”—Ìṣe 2:38-41.
Àwọn ará Samáríà. Nígbà tó yá, wọ́n rán Pétérù lọ sí Samáríà. b Ó tún lo kọ́kọ́rọ́ Ìjọba náà níbẹ̀, nígbà tí òun àti àpọ́sítélì Jòhánù “gbàdúrà fún wọn kí wọ́n lè gba ẹ̀mí mímọ́.” (Ìṣe 8:14-17) Èyí ṣí ọ̀nà fún àwọn ará Samáríà kí wọ́n lè wọ Ìjọba náà.
Àwọn Kèfèrí. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tí Jésù kú, Ọlọ́run fi han Pétérù pé àwọn Kèfèrí (ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Júù) náà máa láǹfààní láti wọ Ìjọba náà. Pétérù wá lo ọ̀kan nínú àwọn kọ́kọ́rọ́ yìí, ní ti pé ó wàásù fáwọn Kèfèrí, ìyẹn sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn láti gba ẹ̀mí mímọ́, kí wọ́n di Kristẹni, kí wọ́n sì nírètí àtiwọ Ìjọba náà.—Ìṣe 10:30-35, 44, 45.
Kí ló túmọ̀ sí láti “wọ Ìjọba náà”?
Àwọn tó bá “wọ Ìjọba náà” máa bá Jésù jọba lọ́run. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa “jókòó lórí ìtẹ́,” wọ́n á sì “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.”—Lúùkù 22:29, 30; Ìṣípayá 5:9, 10.
Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní nípa àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba
Èrò tí kò tọ́: Pétérù ló ń pinnu àwọn tó máa lọ sọ́run.
Òótọ́: Bíbélì ò sọ pé Pétérù ni, ohun tó sọ ni pé Kristi Jésù ló máa “ṣèdájọ́ àwọn alààyè àti òkú.” (2 Tímótì 4:1, 8; Jòhánù 5:22) Kódà, Pétérù fúnra ẹ̀ sọ pé Jésù ni “Ẹni tí Ọlọ́run ti fàṣẹ gbé kalẹ̀ . . . pé kí ó jẹ́ onídàájọ́ alààyè àti òkú.”—Ìṣe 10:34, 42.
Èrò tí kò tọ́: Àwọn ará ọ̀run máa ń dúró kí Pétérù pinnu ìgbà tó máa lo àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba náà.
Òótọ́: Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba, ó sọ fún Pétérù pé: “Ohunkóhun tí ìwọ bá dè ní ayé, a ó sì dè é ní ọ̀run; ohunkóhun tí ìwọ bá tú ní ayé, a ó sì tú u ní ọ̀run.” (Mátíù 16:19, Bíbélì Mímọ́) Báwọn kan ṣe lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sí ni pé Pétérù ló ń pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́run. Àmọ́ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n fi kọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi hàn pé dípò kí Pétérù pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́run, ohun tí wọ́n bá ti pinnu lọ́run ni Pétérù máa ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe. c
Àwọn ẹsẹ míì nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Pétérù gbàṣẹ lọ́run nígbà tó fẹ́ lo àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba náà. Bí àpẹẹrẹ, ó tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún un nígbà tó ń lo kọ́kọ́rọ́ kẹta.—Ìṣe 10:19, 20.
a Nígbà míì, Bíbélì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà, “kọ́kọ́rọ́” láti ṣàpẹẹrẹ àṣẹ àti ojúṣe tí ẹnì kan ní.—Aísáyà 22:20-22; Ìṣípayá 3:7, 8.
b Ẹ̀sìn táwọn ará Samáríà ń ṣe yàtọ̀ sí ẹ̀sìn Júù, àmọ́ wọ́n máa ń tẹ̀ lé àwọn ohun kan tí Òfin Mósè sọ.
c Wo àlàyé tó wà lórí Mátíù 16:19 nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (Study Edition) lédè Gẹ̀ẹ́sì.