Ṣé Mo Lè Rí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Máa Tù Mí Nínú Nínú Bíbélì?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bẹ́ẹ̀ ni. (Róòmù 15:4) Ẹ jẹ́ ká wo díè lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ti tu ọ̀pọ̀ nínú lásìkò tí wọ́n ní ìṣòro tó ń kó wọ́n lọ́kàn sókè.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa
Ìṣòro tó lágbára
Sáàmù 23:4: “Bí mo tilẹ̀ ń rìn nínú àfonífojì tó ṣókùnkùn biribiri, mi ò bẹ̀rù ewukéwu, nítorí o wà pẹ̀lú mi.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Tó o bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, tó o sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, wàá nígboyà láti kojú àwọn ìṣòro tó bá yọjú.
Fílípì 4:13: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run lè fún ẹ lókun láti fara da ìṣòro èyíkéyìí tó o bá dojú kọ.
Ikú ẹni tó o nífẹ̀ẹ́
Oníwàásù 9:10: “Kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú, ibi tí ìwọ ń lọ.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Àwọn tó ti kú ò jẹ̀rora, wọn ò sì lè pa wá lára torí pé wọn ò mọ nǹkan kan mọ́.
Ìṣe 24:15: “Àjíǹde . . . yóò wà.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run lè jí àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde.
Kéèyàn máa dára ẹ̀ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ
Sáàmù 86:5: “Nítorí pé ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, a o sì ṣe tán láti dárí jini; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè ọ́ pọ̀ gidigidi.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run máa ń dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tí wọ́n sì pinnu pé àwọn ò ní ṣe irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
Sáàmù 103:12: “Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Tí Ọlọ́run bá ti dárí jì wá, kì í rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́. Kì í sì í fi àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn jẹ wá níyà.
Ìbànújẹ́
Sáàmù 31:7: “O ti rí ìpọ́njú mi; o mọ ìdààmú ńlá tó bá mi.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run mọ gbogbo ohun tó ò ń bá yí. Ó mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ báwọn míì ò tiẹ̀ mọ̀ ọ́n.
Sáàmù 34:18: “Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa dúró tiẹ̀ lásìkò tí inú ẹ ò bá dùn. Ó lè fún ẹ lókun láti fara da ìnira.
Àìsàn
Sáàmù 41:3: “Jèhófà yóò fún un lókun lórí ibùsùn àìsàn rẹ̀.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run lè fún ẹ lókun kó o lè fara da àìsàn tó lágbára, á sì tún fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀. Bákan náà, ó lè fún ẹ ní ọgbọ́n tó o nílò kó o lè ṣèpinnu tó tọ́.
Àìsáyà 33:24: “Kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: “Ara mi ò yá.’”
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run ṣèlérí pé láìpé gbogbo èèyàn máa gbádùn ìlera tó jí pépé.
Ìdààmú ọkàn
Sáàmù 94:19: “Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, o tù mí nínú, o sì tù mí lára.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Tá a bá yíjú sí Ọlọ́run nígbà tá a bá ní ìdààmú ọkàn, ó máa fi wá lọ́kàn balẹ̀.
1 Pétérù 5:7: “Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Ó máa ń dun Ọlọ́run tó bá rí i tá à ń jìyà. Ó sì rọ̀ wá pé ká gbàdúrà sí òun nípa àwọn ìṣòro wa.
Ogun
Sáàmù 46:9: “Ó ń fòpin sí ogun kárí ayé.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ogun táwọn èèyàn ń jà.
Sáàmù 37:11, 29: “Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé, inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà. . . . Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Àwọn olódodo máa gbádùn àlááfíà títí láé lórí ilẹ̀ ayé.
Àníyàn nípa ọjọ́ iwájú
Jeremáyà 29:11: “‘Mo mọ èrò tí mò ń rò nípa yín dáadáa,’ ni Jèhófà wí, ‘èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.’”
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run fi dá àwọn èèyàn ẹ̀ lójú pé kí wọ́n fọkàn balẹ̀ ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.
Ìfihàn 21:4: “Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run ṣèlérí pé láìpẹ́ àwọn ohun búburú tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí máa di ohun àtijọ́.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”