Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Gbígbẹ̀san?
Ohun Tí Bíbélì Sọ
A lè ronú pé kò burú láti gbẹ̀san, àmọ́ èrò yẹn ò bá ohun tí Bibélì sọ mu. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Má sọ pé: ‘Bó ṣe ṣe sí mi ni màá ṣe sí i pa dà; Màá ṣe bákan náà sí i.” (Òwe 24:29, àlàyé ìsàlẹ̀) Ìmọ̀ràn Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti yẹra fún gbígbẹ̀san.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa
Kí nìdí tó fi burú kéèyàn gbẹ̀san?
Tí ẹnìkan bá ṣe ohun tó dùn wá tàbí tó hùwà ìkà sí wa, inú máa ń bí wa, a sì máa ń fẹ́ kí ẹni yẹn jìyà ohun tó ṣe sí wa. Àmọ́, Bíbélì ò sọ pé ká fúnra wa gbẹ̀san. Kí nìdí?
Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa gbẹ̀san, kódà inú rẹ̀ kì í dùn tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhófà a Ọlọ́run sọ nínú Bibélì pé: “Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san.” (Róòmù 12:19) Bíbélì gba àwọn tí wọ́n hùwà àìdáa sí nímọ̀ràn pé kí wọ́n wá bí wọ́n á ṣe yanjú ọ̀rọ̀ náà ní ìtùnbí-ìnùbí dípò kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe gbẹ̀san. (Róòmù 12:18) Àmọ́ kí la tún lè ṣe lẹ́yìn tá a ti sa gbogbo ipá wa kí àlàáfíà lè jọba? Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ náà.—Sáàmù 42:10, 11.
Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ń fìyà jẹ ẹni tó bá ṣẹ̀?
Ní báyìí, Ọlọ́run ṣì fàyè gba àwọn aláṣẹ láti fìyà jẹ ẹni tó bá ṣe ohun tó burú. (Róòmù 13:1-4) Láìpẹ́, ó máa ṣèdájọ́ gbogbo àwọn oníwà ìkà, ó sì máa fòpin sí ìyà títí láé.—Àìsáyà 11:4.
Kí ni mo lè ṣe tó bá ń ṣe mí bíi pé kí n gbẹ̀san?
Máa fara balẹ̀. (Òwe 17:27) Àwọn tó máa ń tètè bínú sábà máa ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n á pa dà wá kábàámọ̀. Àmọ́ àwọn tó ń fara balẹ̀ ronú kí wọ́n tó ṣe nǹkan sábà máa ń ṣe àwọn ìpinnu tó dáa.—Òwe 29:11.
Rí àrídájú ọ̀rọ̀. (Òwe 18:13) Ó yẹ kí ẹni tí wọ́n hùwà àìdáa sí bi ara ẹ̀ láwọn ìbéèrè bíi, ‘Kí ló mú kí ẹni tó hùwà tí kò dáa sí mi yìí ṣe ohun tó ṣe? Ṣé ara ń kan án ni? Àbí kò mọ̀ọ́mọ̀?’ Nígbà míì, a lè rò pé ẹnì kan mọ̀ọ́mọ̀ ṣe nǹkan, àmọ́ kó jẹ́ pé ẹni náà kàn ṣe àṣìṣe ni.
Ohun táwọn kan rò nípa gbígbẹ̀san
Ohun táwọn kan rò: Bíbélì fọwọ́ sí i pé ká máa gbẹ̀san torí ó sọ pé, “ojú dípò ojú.”—Léfítíkù 24:20.
Òtítọ́: Òfin “ojú dípò ojú” tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ìsírẹ́lì ò túmọ̀ sí pé kí wọ́n máa gbẹ̀san fúnra wọn. Òfin yìí ń jẹ́ kí àwọn adájọ́ lè fi ìyà tó tọ́ jẹ ẹni tó ṣẹ̀. b—Diutarónómì 19:15-21.
Ohun táwọn kan rò: Torí pé Bíbélì ò fọwọ́ sí kéèyàn máa gbẹ̀san, a ò lè gbèjà ara wa tí wọ́n bá gbéjà kò wá.
Òtítọ́: Tí wọ́n bá gbéjà kò wá, a lẹ́tọ̀ọ́ láti gbèjà ara wa tàbí sọ fún àwọn aláṣẹ kí wọ́n gbèjà wa. Àmọ́, Bíbélì sọ pé ká yẹra fún ìwà ipá bó bá ti lè ṣeé ṣe tó.—Òwe 17:14.
a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.
b Tó o bá fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa òfin yìí, wo àpilẹ̀kọ náà, Kí Ni Ìtumọ̀ “Ojú fún Ojú?”