Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Sísun Òkú?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì ò fún wa ní ìtọ́ni kan pàtó lórí ọ̀rọ̀ fífi iná sun òkú. Kò sí òfin kankan nínú Bíbélì tó dá lórí sísin òkú tàbí fífi iná sun ún.
Àmọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tí wọ́n sin òkú èèyàn wọn. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù sapá gidigidi kó lè ra ibi tó máa sin òkú Sérà ìyàwó rẹ̀ sí.—Jẹ́nẹ́sísì 23:2-20; 49:29-32.
Bíbélì tún mẹ́nu ba àwọn olóòótọ́ èèyàn tó sun òkú àwọn míì nínú iná. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ọ̀tá pa Sọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì àti mẹ́ta nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sójú ogun, ilẹ̀ àwọn ọ̀tá ni wọ́n kú sí, wọn ò sì palẹ̀ òkú wọn mọ́. Nígbà táwọn olóòótọ́ ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ jagunjagun gbọ́, wọ́n lọ gbé òkú Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ rẹ̀ kúrò níbẹ̀, wọ́n dáná sun àwọn òkú náà, wọ́n sì fi iyẹ̀pẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 31:8-13) Bíbélì jẹ́ ká rí i pé ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn ṣe sí àwọn òkú náà rí ìtẹ́wọ́gbà.—2 Sámúẹ́lì 2:4-6.
Àṣìlóye táwọn èèyàn sábà máa ń ní nípa sísun òkú
Àṣìlóye: Nǹkan ẹ̀sín ni téèyàn bá dáná sun òkú.
Òtítọ́: Bíbélì sọ pé àwọn tó bá kú máa pa dà di erùpẹ̀, ohun tó sì máa ń ṣẹlẹ̀ nìyẹn tí òkú kan bá ti jẹrà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Tí wọ́n bá dáná sun òkú, ṣe ló máa jẹ́ kó tètè di eérú, tàbí erùpẹ̀, dípò kó kọ́kọ́ jẹrà.
Àṣìlóye: Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn tí kò rí ojúure Ọlọ́run nìkan ni wọ́n máa ń dáná sun òkú wọn.
Òtítọ́: Wọ́n dáná sun òkú àwọn èèyàn kan tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́, bí Ákánì àti ìdílé rẹ̀. (Jóṣúà 7:25) Àmọ́ ìyẹn kàn wáyé bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe ohun tí òfin sọ pé kí wọ́n máa ṣe fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nìyẹn. (Diutarónómì 21:22, 23) Bá a ṣe sọ ṣáájú, wọ́n dáná sun òkú àwọn kan tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, bíi Jónátánì tó jẹ́ ọmọ Sọ́ọ̀lù Ọba.
Àṣìlóye: Tí wọ́n bá dáná sun òkú ẹnì kan, Ọlọ́run ò ní lè jí i dìde.
Òtítọ́: Tó bá dọ̀rọ̀ àjíǹde àwọn òkú, kò sí òkú tí Ọlọ́run ò lè jí dìde, ì báà jẹ́ èyí tí wọ́n sin, èyí tí wọ́n dáná sun, èyí tó bómi lọ tàbí tí ẹran igbó jẹ. (Ìfihàn 20:13) Kò ná Olódùmarè ní nǹkan kan láti dá ara tuntun fún ẹni náà.—1 Kọ́ríńtì 15:35, 38.