Kí Ni Bíbélì Jẹ́ Ká Mọ̀ Nípa Àjàkálẹ̀ Àrùn?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá di ọjọ́ ìkẹyìn, àjàkálẹ̀ àrùn (àwọn àrùn tó ń ranni, àtàwọn àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí) máa wà. (Lúùkù 21:11) Ọlọ́run kọ́ ló ń fi àwọn àrùn yìí jẹ àwọn èèyàn níyà. Kódà, láìpẹ́ Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti fòpin sí gbogbo àìsàn títí kan àjàkálẹ̀ àrùn.
Ṣé Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àjàkálẹ̀ àrùn máa wà?
Bíbélì ò dárúkọ àwọn àrùn kan ní pàtó, irú bí àrùn corona, AIDS, tàbí àrùn gágá. Àmọ́ ó sọ tẹ́lẹ̀ pé “àjàkálẹ̀ àrùn” máa wà. (Lúùkù 21:11; Ìfihàn 6:8) Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ àmì pé a ti wà ní “ọjọ́ ìkẹyìn” tàbí “ìparí ètò àwọn nǹkan.”—2 Tímótì 3:1; Mátíù 24:3.
Ṣé Ọlọ́run ti fi àrùn kọ lu àwọn èèyàn rí?
Láwọn ìgbà kan, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run fi àrùn kọ lu àwọn èèyàn kó lè fi jẹ wọ́n níyà. Bí àpẹẹrẹ, ó fi àrùn ẹ̀tẹ̀ kọ lu àwọn kan. (Nọ́ńbà 12:1-16; 2 Àwọn Ọba 5:20-27; 2 Kíróníkà 26:16-21) Àmọ́, Ọlọ́run ò jẹ́ kí àrùn náà tàn dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ò mọwọ́mẹsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, kìkì àwọn tó ṣàìgbọràn nìkan ni Ọlọ́run fi àrùn náà dá lẹ́jọ́.
Ṣé Ọlọ́run ló ń fa àjàkálẹ̀ àrùn tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí?
Rárá. Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run ló ń fi àjàkálẹ̀ àrùn àti àìsàn tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí jẹ àwọn èèyàn níyà. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ kọ́ nìyẹn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
Òótọ́ kan ni pé, àìsàn ti fojú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan rí màbo nígbà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe rí lónìí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé “àìsàn lemọ́lemọ́” máa ń ṣe Tímótì tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. (1 Tímótì 5:23) Àmọ́, Bíbélì ò sọ pé torí wọ́n ṣẹ Ọlọ́run ni àìsàn náà fi ṣe wọ́n. Bákan náà lónìí, àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń ṣàìsàn, wọ́n sì lè kó àrùn. Èyí máa ń ṣẹlẹ̀ torí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣèèṣì wà níbi kan nígbà tí kò yẹ kí wọ́n wà níbẹ̀.—Oníwàásù 9:11.
Ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ni pé kò tíì tó àkókò tí Ọlọ́run máa fìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ́ pé “ọjọ́ ìgbàlà” làkókò tá a wà yìí, tó túmọ̀ sí pé àkókò yìí gan-an ni Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn èèyàn wá mọ òun, kí wọ́n lè rí ìgbàlà. (2 Kọ́ríńtì 6:2) Ọ̀nà kan tí Ọlọ́run gbà ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni ìròyìn ayọ̀ tá à ń wàásù rẹ̀ kárí ayé, tí Bíbélì pè ní “ìhìn rere Ìjọba” Ọlọ́run.—Mátíù 24:14.
Ṣé àjàkálẹ̀ àrùn máa dópin?
Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé lọ́jọ́ iwájú àwọn èèyàn ò ní ṣàìsàn mọ́. Tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, Ọlọ́run máa mú gbogbo àìsàn kúrò. (Àìsáyà 33:24; 35:5, 6) Ó máa mú ìyà, ìrora àti ikú kúrò. (Ìfihàn 21:4) Ó sì tún máa jí àwọn tó ti kú dìde kí wọ́n lè ní ara tó jí pépé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Sáàmù 37:29; Ìṣe 24:15.
Ohun tí Bíbélì sọ nípa àìsàn
Mátíù 4:23: “[Jésù] lọ káàkiri gbogbo Gálílì, ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, ó ń wo onírúurú àìsàn àti onírúurú àìlera sàn láàárín àwọn èèyàn.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká rí i pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé.
Lúùkù 21:11: “Àjàkálẹ̀ àrùn . . . máa wà.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Àwọn àìsàn tó ń bá aráyé fínra fi hàn pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí.
Ìfihàn 6:8: “Wò ó! mo rí ẹṣin ràndánràndán kan, Ikú ni orúkọ ẹni tó jókòó sórí rẹ̀. Isà Òkú sì ń tẹ̀ lé e pẹ́kípẹ́kí. A sì fún wọn ní àṣẹ . . . pé kí wọ́n fi . . . àjàkálẹ̀ àrùn pani.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin inú ìwé Ìfihàn jẹ́ ká mọ̀ pé àjàkálẹ̀ àrùn máa wà lákòókò wa yìí.