Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ọlọ́run?
Ohun tí Bíbélì sọ
Tó o bá fẹ́ mọ Ọlọ́run, ó yẹ kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀, kó o sì máa ṣe àwọn ohun tó máa múnú ẹ̀ dùn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run máa “sún mọ́ ẹ.” (Jémíìsì 4:8) Bíbélì fi dá wa lójú pé “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:27.
Àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe kó o lè mọ Ọlọ́run
Máa ka Bíbélì
Ohun tí Bíbélì sọ: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.”—2 Tímótì 3:16.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run ló ni Bíbélì. Èrò rẹ̀ sì ni àwọn tó kọ Bíbélì kọ sílẹ̀. Inú ìwé tó sàrà ọ̀tọ̀ yìí nìkan la ti lè mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Bíbélì yìí kan náà ló sọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ fún wa, pé ó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, onídàájọ́ òdodo àti aláàánú.—Ẹ́kísódù 34:6; Diutarónómì 32:4.
Ohun tó o lè ṣe: Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. (Jóṣúà 1:8) Ronú nípa ohun tó o kà, kó o sì bi ara ẹ pé: ‘Kí ni ohun tí mo kà yìí kọ́ mi nípa Ọlọ́run?’—Sáàmù 77:12.
Bí àpẹẹrẹ, o lè ka Jeremáyà 29:11, kó o wá bi ara ẹ pé: ‘Èrò wo ni Ọlọ́run ní sí mi, ṣé ti àlàáfíà ni àbí ti àjálù? Ṣé Ọlọ́run máa fìyà ohun tí mo ṣe jẹ mí lọ́jọ́ iwájú àbí ṣe ló fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la mi dáa?
Máa kíyè sí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá
Ohun tí Bíbélì sọ: “Àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá.”—Róòmù 1:20.
Ohun tó túmọ̀ sí: Àwọn ohun tí Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́. Ṣe ló dà bí ìgbà tá a bá rí àwòrán kan tó rẹwà tẹ́nì kan yà tàbí ẹ̀rọ tó ń dárà tẹ́nì kan ṣe, a máa gbà pé iṣẹ́ ọpọlọ ni onítọ̀hún ṣe, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bí àpẹẹrẹ, ọ̀nà tí ọpọlọ àwa èèyàn gbà ń ṣiṣẹ́ díjú gan-an, ó sì lè gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsọfúnni, èyí fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Bákan náà, bí oòrùn àti ìràwọ̀ ṣe lágbára jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run náà lágbára.—Sáàmù 104:24; Àìsáyà 40:26
Ohun tó o lè ṣe: Máa kíyè sí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Bí o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, bi ara ẹ pé, ‘Kí ni àwọn ohun àgbàyanu tí mo rí yìí kọ́ mi nípa Ọlọ́run?’ a Òótọ́ ni pé, kì í ṣe gbogbo nǹkan la lè kọ́ nípa Ọlọ́run látinú àwọn nǹkan tó dá. Ìdí nìyẹn tó fi fún wa ní Bíbélì.
Máa lo orúkọ Ọlọ́run
Ohun tí Bíbélì sọ: “Màá dáàbò bò ó torí pé ó mọ orúkọ mi. Yóò ké pè mí, màá sì dá a lóhùn.”—Sáàmù 91:14, 15.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run, tí orúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, máa ń kíyè sí àwọn tó mọ orúkọ ẹ̀, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún un. b (Sáàmù 83:18; Málákì 3:16) Bí Ọlọ́run ṣe sọ orúkọ ẹ̀ fún wa fi hàn pé ó fẹ́ ká mọ òun, ó sọ pé. “Èmi ni Jèhófà. Orúkọ mi nìyẹn.”—Àìsáyà 42:8.
Ohun tó o lè ṣe: Máa lo orúkọ Jèhófà tó o bá ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run.
Máa gbàdúrà sí Jèhófà
Ohun tí Bíbélì sọ: “Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é.”—Sáàmù 145:18.
Ohun tó túmọ̀ sí: Jèhófà máa ń sún mọ́ àwọn tó ń gbàdúrà sí i, tí wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. Àdúrà jẹ́ apá kan ìjọsìn wa, ó sì tún fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.
Ohun tó o lè ṣe: Máa gbàdúrà sí Ọlọ́run nígbà gbogbo. (1 Tẹsalóníkà 5:17) Sọ àwọn ìṣòro ẹ fún Ọlọ́run, kó o sì sọ bó ṣe rí lára ẹ fún un.—Sáàmù 62:8. c
Jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú Ọlọ́run túbọ̀ jinlẹ̀
Ohun tí Bíbélì sọ: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa.”—Hébérù 11:6.
Ohun tó túmọ̀ sí: Tá a bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, ti pé a mọ̀ pé Ọlọ́run wà ò túmọ̀ sí pé a nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. Tá a bá nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, a máa gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá, àá gbà pé gbogbo ìlérí rẹ̀ ló máa ṣẹ, àá sì gbà pé àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ ló dáa jù. Ó ṣe tán, tá ò bá fọkàn tán ẹnì kan, a ò lè dòrẹ́ onítọ̀hún.
Ohun tó o lè ṣe: Ká tó lè ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀, ó yẹ ká ní ìmọ̀ Bíbélì. (Róòmù 10:17) Torí náà, máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí á jẹ́ kó o lè gbárá lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. d
Máa ṣe ohun táá múnú Ọlọ́run dùn
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí nìyí, pé ká pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”—1 Jòhánù 5:3.
Ohun tó túmọ̀ sí: Jèhófà máa ń sún mọ́ àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń sapá láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.
Ohun tó o lè ṣe: Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, máa kíyè sí àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àtàwọn ohun tí kò fẹ́. Wá bi ara ẹ pé, ‘Kí làwọn ohun tí mo lè ṣe kí n lè múnú Ọlọ́run dùn?’—1 Tẹsalóníkà 4:1.
Máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run kó o lè rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé ẹni rere ni Jèhófà.”—Sáàmù 34:8.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run fẹ́ kó o mọ̀ pé ẹni rere lòun. Tó o bá rí bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ ẹ tó, tó o sì rí i bó ṣe ń tì ẹ́ lẹ́yìn, á máa wù ẹ́ láti sún mọ́ ọn.
Ohun tó o lè ṣe: Bó o ṣe ń ka Bíbélì, máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, wàá sì rí i bó ṣe máa ṣe ẹ́ láǹfààní. (Àìsáyà 48:17, 18) Yàtọ̀ síyẹn, máa kíyè sí àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tó ti kojú ìsòro kan tàbí òmíì, wo bí Ọlọ́run ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ẹ̀, tí ìgbésí ayé wọn dáa sí i, tí àlàáfíà gbilẹ̀ nínú ìdílé wọn, tí ìyẹn sì ń jẹ́ kí wọ́n láyọ̀. e
Èrò tí kò tọ́ táwọn kan ní nípa Ọlọ́run
Èrò tí kò tọ́: Àwọn kan rò pé àwọn ò lè sún mọ́ Ọlọ́run, torí ó tóbi lọ́ba ó sì lágbára.
Òótọ́ ibẹ̀: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ló tóbi jù tó sì lágbára jù lọ láyé àti lọ́run, síbẹ̀ ó ń rọ̀ wá pé ká sún mọ́ òun. Ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́.—Ìṣe 13:22; Jémíìsì 2:23.
Èrò tí kò tọ́: Àwọn kan rò pé àdììtú ni Ọlọ́run, torí náà a ò lè mọ̀ ọ́n.
Òótọ́ ibẹ̀: Àwọn nǹkan kan wà nípa Ọlọ́run tí ò le yé wa torí pé Ẹ̀mí ni, a ò lè fojú rí i. Síbẹ̀, a lè mọ Ọlọ́run. Kódà, Bíbélì sọ pé a gbọ́dọ̀ mọ Ọlọ́run ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 17:3) Bíbélì ṣàlàyé lọ́nà tó rọrùn nípa Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa, ó jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́, àwọn nǹkan tó máa ṣe fáwa èèyàn, bó ṣe máa tún ayé yìí ṣe àti àwọn ìlànà tó fẹ́ ká máa tẹ̀ lé. (Àìsáyà 45:18, 19; 1 Tímótì 2:4) Bákan náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Torí náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé a lè mọ Ọlọ́run, kódà, a lè sún mọ́ ọn.—Jémíìsì 4:8.
a Wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” kó o lè rí i bí àwọn ohun tí Ọlọ̀run dá ṣe fi hàn pé ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n
b Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé orúkọ Jèhófà túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di.” Bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ ká mọ orúkọ ẹ̀, ṣe ló ń sọ fún wa pé: ‘Màá di ohunkóhun kí ìfẹ́ mi àtàwọn ohun tí mo ní lọ́kàn lè ṣẹ. Màá mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.’
c Wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ọlọ́run Á Gbọ́ Àdúrà Mi?”
d Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo fídíò náà Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
e Wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà.”