Ṣé Ọlọ́run Ló Dá Èṣù?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì sọ pé Ọlọ́run kọ́ ló dá Èṣù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni tí Ọlọ́run dá ló di Èṣù. Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé: “Pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; Olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:3-5) Látinú ọ̀rọ̀ yìí, a lè rí i pé Sátánì Èṣù jẹ́ ẹni pípé àti olódodo nígbà kan rí, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.
Ní Jòhánù 8:44, Jésù sọ pé Èṣù ‘kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́,’ tó túmọ̀ sí pé Sátánì ti fìgbà kan rí jẹ́ olóòótọ́ àti aláìlẹ́gàn.
Àmọ́, bíi ti ìyókù àwọn áńgẹ́lì Jèhófà tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n, áńgẹ́lì tó di Sátánì ní òmìnira láti yan ohun tó dára tàbí ohun tí kò dára. Nígbà tó yàn láti máa tako Ọlọ́run tó sì mú kí tọkọtaya àkọ́kọ́ dara pọ̀ mọ́ òun, ó sọ ara rẹ̀ di Sátánì, tó túmọ̀ sí “Alátakò”—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5; Ìṣípayá 12:9.